US Election 2020: Wo ìyàtọ̀ láàrin ìjọba Joe Biden sí ti Donald Trump bó ṣe kan orílẹ̀èdè àgbáyé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ohun akọkọ ti ijọba aarẹ orilẹede Amerika labẹ Aarẹ Donald Trump kọkọ ṣe nigba ti wọn de ipo ni lati fihan agbaye pe orilẹede Amerika ni yoo saju ninu ohun gbogbo,'America First'.

Aarẹ Donald Trump tako awọn adehun ti wọn ṣe pẹlu awọn orilẹede miran lagbaye, ti o si gbe igbesẹ bi o ṣe wu u lai naani idọrẹpọ laarin orilẹede.

Amọ, aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Joe Biden ti ni igbesẹ ti oun yoo yatọ patapata si aarẹ Trump, o ni gbogbo idọrẹpọ pẹlu orilẹede to ṣe pataki lagbaye, ti aarẹ Trump gbegile ni oun yoo tun to pada.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn ohun ti Joe Biden yoo ṣe ni lati ṣe atunṣe pẹlu Ajọ NATO lagbaye.

Bakan naa ni orilẹede Amẹrika yoo pada si Ajọ Eto Ilera lagbaye, ki wọn si saaju igbogun ti aarun Coronavirus.

IYATỌ OJU ỌJỌ:

Joe Biden ni oun yoo pada si adehun ti orilẹede Amẹrika ni pẹlu agbaye lori idẹkun oju ọjọ gbigbona, eleyii ti wọn pe ni 'Paris Climate Change.'

Eleyii jẹ ọkan lara awọn adehun ti aarẹ Donald Trump tako, to si yọ orilẹede Amerika kuro ninu adehun naa.

IRAN:

Joe Biden ti ni oun ṣetan lati ṣe adehun miran papọ pẹlu awọn orilẹede agbaye lati le mu idẹrun ba orilẹede Amerika lori ọrọ aje wọn ti aarẹ Donald Trump fofin de.

Ọdun 2018 ni Aarẹ Trump yọ orilẹede Amẹrika kuro ninu adehun ti wọn ni pẹlu Iran lati jẹ ki wọn dẹwọ ipese ija ogun ọlọgọọrọ, Nuclear.

ORILẸEDE YEMEN:

Joe Biden ni oun yoo tọ ipasẹ aarẹ Trump lati fopin si iranwọ orilẹede Amẹrika pẹlu ogun abẹle lorilẹede Yemen.

Lẹyin ti awọn eniyan paapaa awọn aṣofin lorileede Amerika koju oro si, nitori ọpọ ẹmi to ti ṣofo ninu ogun abẹle Yemen naa.

IJA LAARIN ILẸ ARAB ATI ISREAL:

Joe Biden ti ni oun yoo tẹlẹ ipasẹ aarẹ Donald Trump ninu adehun rẹ pẹlu orilẹede United Arab Emirates, nitori Biden fẹran orilẹede Isreal.

Amọ, o ni awọn yoo ṣe agbeyẹwo agbegbe 'West Bank' to n fa ija laarin oriḷede Palestine ati Isrẹli fun ọpọlọpọ ọdun bayii.

RUSSIA:

Bi o tilẹ jepe aarẹ Donald Trump fẹran aarẹ orilẹede Russia, Vladmir Putin, to si ṣetan lati dariji i.

Amọ, Joe Biden ni awọn ṣẹṣẹ bẹrẹ pẹlu orilẹede Russia, nitori awọn yoo ṣewadii bi wọn ṣe tọwọbọ eto idibo wọn ni ọdun 2016.

Bakan naa ni wọn sọ wi pe awọn yoo gbe tẹsiwaju lati fofin ọrọ aje ilẹ Russia,

Joe Biden ni o dun mọ oun ninu bi o ṣe waye bẹẹ labẹ aarẹ Donald Trump, ti yoo si tẹsiwaju ni abẹ iṣejọba oun.

CHINA:

Ni ọdun 2017, aarẹ Donald Trump ṣe apejuwe adari ilẹ China, Xi Jinping gẹgẹ bi ọrẹ oun ti awọn si jọ fẹran ounjẹ aladun bii sokoleeti.

Amọ, ija waye laarin wọn pẹlu bi aaṛẹ Trump ṣe ni China lo n pin arun Coronavirus kaakiri lagbaye, ati bi China ṣe n gba ọrọ aje wọ Amẹrika lọwọ.

Joe Biden ni awọn ko ni tọ ipasẹ Donald Trump, awọn yo ran orilẹede China lọwọ lori ọrọ aje wọn ati lati mu ibasepọ to dan mọran waye laarin awọn orilẹede mejeeji.

Jijawe olubori Joe Biden jẹ ibori imọlẹ lori okunkun - Obasanjo

Aarẹ ana lorileede Naijira Olusegun Obasanjo ti pẹlu awọn olori kọọkan lagbaye to n fi ikini ku oriire ranṣẹ si Joe Biden to jaweolubori ninu idibo Amẹrika.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ fi sita, Obasanjo ni aṣeyọri Biden jẹ aṣeyọri daada lori aburu ati pe aṣeyọri Biden kii ṣe ti Amrika nikan bi kii ṣe ti gbogbo agbaye.

Bẹẹ naa ni Obasanjo ba Kamala Harris yọ gẹgẹ bi obinrin alawọdudu akọkọ ti yoo de ipo igbakeji aarẹ Amẹrika.

Yatọ si Obasanjọ, olootu ijọba Canada Justin Trudeau, Taoiseach Micheál Martin ti Ireland ati Keir Starmer olori alatakọ nilẹ Gẹẹsi fi ọrọ ikini ranṣẹ loju opo Twitter

Titi di igba ta fi n ko iroyin yi jọ, olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson, aarẹ Russia Vladmir Putin ati aarẹ Naijiria Muhammadu Buhari ko ti fi ikini ranṣ si Biden ati Harris.

Kini Trump sọ?

Aarẹ Donald Trump ti fesi si iroyin pe alatako rẹ Joe Biden lo jaweolubori ninu idibo aarẹ ilẹ Amẹrika.

Ninu atẹjade to wa lati ọdọ awọn agbẹnusọ rẹ, Trump ni ''gbogbo wa la mọ idi ti Biden fi n sare lati kede ara rẹ gẹgẹ bi ẹni to jaweloubor ti awọn eeyan rẹ nileeṣẹ iroyin naa si n ṣapa lati ran lọwọ.Wọn ko fẹ ki ododo jade ni''

Trump wa poinu pe bẹrẹ lati ọjọ Aje to n bọ, oun yoo gba ileẹjọ lọ lati ri pe wọn tẹle ofin idibo ti ẹni to jaweolubori si fidi sori aga.

Trump ko ni aridaju gbogbo ọrọ rẹ to n sọ pe awọn eeyan Biden n gbiyanju pe ki wọn ka ibo toun ti pe wọn ko jẹ ibo to tọ.

Ohun ta gbọ ni pe Aarẹ Trump wa nibi to ti n gba ''gọọfu'' nigba ti iroyin ikede afojusun pe Biden wọle ipo aarẹ kan lara.

Biden la Trump mọ́lẹ̀ wọlé ìbò ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

Oludije ẹgbẹ oṣelu Democrat Joe Biden lo wọle ibo aarẹ orilẹ-ede Amẹrika.Biden la oludije ẹgbẹ Republican Donald Trump mọlẹ ninu eto idibo tawọn ọmọ ilẹ Amẹrika ti tu yaya tu yaya jade.Biden ni ibo awọn aṣoju 273 nigba ti Trump ni 214 eyi to fihan gbangba pe Biden lawọn ọmọ orileede Amẹrika lati tukọ ilẹ naa fun ọdun mẹrin tó n bọ.

Awọn ipinlẹ to ṣe pataki bíi Pennsyvannia, Georgia, Michigan, Wisconsin, Nevada ati Arizona ni Biden ati Trump ti jọ figa gbaga ninu eto idibo ọhun.Lati Ọjọru ni Trump ti sọ pe oun lo jawe olubori ninu eto idibo ọhun nigba ti Biden naa ni o da oun loju pe oun yoo bori ninu ibo aarẹ Amẹrika.Biden lo ti ni ibo to pọju julọ ninu itan eto idibo aarẹ orilẹ-ede Amẹrika.Ẹwẹ, Trump fidirẹmi ninu ẹjọ to pe lori kika ibo lawọn ipinlẹ kan.Adajọ ni ko si to le fidi rẹ mulẹ pe magomago wa ninu eto idibo Amẹrika.