You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo ohun tí òṣìṣẹ́ yí ṣe tí ọ̀gá rẹ̀ fi fún ní ẹ̀bùn owó £10 mílíọ̀nù
Ọga ileeṣẹ kan fun ọmọiṣẹ rẹ to n fẹyinti ni ẹbunowo miliọnu mẹwaa pọun owo ilẹ Gẹẹsi lati fi sami ifẹyinti rẹ.
Ẹbun owo ti a n sọrọ rẹ naa wa fun awon ọṣiṣẹ ẹgbẹrun meje ati ẹẹdẹgbẹta ileeṣẹ naa to wa lagbegbe South Wales ati ẹgbẹrun mẹta to wa loke okun.
Ọga agba ileeṣẹ Admiral', David Stevens ati iyawo rẹ, Heather lo gbe ẹbun owo ifẹyinti naa kalẹ.
Awọn oṣiṣẹ kan yoo gba ẹbun owo ẹgbẹrun kan pọun, awọn miran yoo si gba ẹẹdẹgbẹta pọun.
Ọgbẹni Steven pẹlu iyawo rẹ ni wọn jumọ da ileeṣẹ adojutofo ọkọ naa silẹ lọdun 1991.
O ni inu oun dun lati ba awọn oṣiṣẹ naa ṣiṣẹ pọ.
"Lati dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ naa lona ti a gba ṣe yii gan an ni ohun to tọ."
- Ọ̀wọ́ngógó búrẹ́dì gbòde kàn lẹ́yìn tí àwọn oníbúrẹ́dì da iṣẹ́ sílẹ̀
- Èèyàn mẹ́jọ jónà ráúráú nínú ìjàmbá ọkọ̀ akérò tó ṣẹlẹ̀ ní mọ́rosẹ̀ Eko sí Ibadan
- Ọlọ́jọ́ Festival 2020:Ọ̀ọ̀ni ti Ilé Ifẹ̀ tí wọ ìléèdí ọlọjọ méje tí kò ní rí ẹnikẹ́ni sójú
- Ẹ̀yin òṣìṣẹ́ elétò ìlera, ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́- JOHESU
- Wo ìdí tí ètò ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo ṣe lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀
O fi kun un pe "itẹpamọṣẹ wọn ati ifọkansin lẹnu iṣẹ lo mu ki ileeṣẹ Admiral o tubọ goke agba sii lati ibẹrẹ titi di eyi to fi n ni oṣiṣẹ to le ni ẹgbẹrun mọkan bayii kaakiri agbaye."
Olori ileeṣẹ naa tẹlẹ, Henry Englehardt lo ti koko fun ọkọọkan awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa ni ẹgbẹrun kan pọun eyi ti apapọ rẹ bọ si miliọn meje pọun nigba to n fẹyinti lọdun 2016.
Oṣiṣẹ mẹtadinlọgọta ni ileeṣẹ naa fi bẹrẹ gẹgẹ bi ileeṣẹ to n fi ẹ̀rọ ibanisọrọ foonu ta eto adojutofo fawon onibara wọn.
- Wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká tó ṣe ìgbéyàwó ní ọdún 2020 yìí
- Àbájáde ìwádìí ẹlikọ́pítà to já ni Opebi nílùú Eko laipẹ yii ti jáde
- Ẹwọ́n ọdún méjìlá ni wọ́n fún àwọn Ṣója mẹ́rin tó pa ìyá àti ọmọ méjì ní Cameroon
- Owó déé! Ètò ìjọba fún pínpín owó ìrànwọ́ yóò bẹ̀rẹ̀ ni 21/09/2020
- Asiwaju BolaTinubu sọ̀rọ̀ lóríi ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ pé òun gbà pé APC fìdí rẹmi ní Edo
- Lawuyi Ogunniran, àgbà ọ̀jẹ̀ òǹkọ̀wé Eégún Aláré dágbére fáyé!