Tola Ogundipe: Òṣìṣẹ́ mẹ́rin bọ́ sí gbaga ọlọ́pàá lórí ikú ọ̀gá wọn tó rì sómi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Igbakeji Ọga Agba ileeṣẹ to n risi ọrọ owo ori, Price Water Coopers , PwC Nigeria , Tola Ogundipẹ ti jade laye.

Ọjọ Satide ni wọn ti bẹrẹ si ni wa arakunrin naa lẹyin to wọ ọkọ oju omi ni ipinlẹ Eko.

Ọjọ Aiku ni wọn ri ọkọ oju omi naa amọ ti awọn ọlọpaa to n ṣiṣẹ lori omi si ri oku rẹ ni Ọjọ Aje.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Muyiwa Adejọbi sọ wi pe, lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, awọn oṣiṣẹ oloogbe mẹrin ni awọn ti fi ọrọ wa lẹnu wo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O salaye wi pe, Kọmisọna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ti paṣẹ iwadii idakọnkọ lori iṣẹlẹ naa.

'' A ti gbe iṣẹlẹ naa lọ si ẹka to n risi ọrọ iwa ọdaran ni Yaba, nipinlẹ Eko lati ṣe iwadii naa lẹkunrẹrẹ.''

''Ti iwadii ba pari, ileeṣẹ ọlọpaa yoo fi abajade han si gbangba.''

Ninu ọrọ ti ileeṣẹ Price Waterhouse Coopers fi lede, Ọga agba patapata ni Naijiria, Uyi Akpata sapejuwe Ogundipẹ to doloogbe naa, gẹgẹ bi ẹni to n ṣe iṣẹ rẹ doju ami.

Ko to di oloogbe, Tola Ogundipe ṣiṣẹ gẹgẹ bi adari ẹka PwC Africa Tax , Assurance Leader for PwC Africa ati awọn ipo miran to dimu ninu ilẹeṣẹ PwC.

Ileeṣẹ Price Waterhouse Coopers ni awọn yoo fi ọjọ isinku rẹ lede lẹyin ijiroro pẹlu awọn ẹbi ati ara oloogbe naa.