Good luck fish: Ààrẹ Zambia ṣ'èdárò Ẹja akóredé tó papòdà

Aarẹ orile-ede Zambia, Edgar Lungu ti darapọ mọ ogunlọgọ ọmọ ilẹ naa ti wọn n ṣe idaro ẹja nla kan to ku ni fasiti Copperbelt to tobi sikeji lorilẹ ede naa.

Ibanujẹ dori agba kodo ni Fasiti Copperbelt nibi t'awọn akẹkọọ ti tan ina abẹla ti wọn si rin kaakiri ile ewe naa lati kẹdun ẹja Mafishi to jẹ Ọlọrun nipe.

Fun bi ogun ọdun sẹyin, awọn akẹkọọ Fasiti Copperbelt gbagbọ pe ẹja Mafishi maa n gbe ire ko wọn ninu idanwo.

Olori awọn akẹkọọ, Lawrence Kasonde ṣalaye pe o to ọdun mejilelogun ki o to jade laye, ati pe ẹja naa ti gbe inu omi lọgba fasiti Copperbelt fun ogun ọdun o kere tan.

Kasonde fikun ọrọ rẹ pe iwadii si n lọ lọwọ lori ohun to ṣekupa ẹja akorede ọhún.

Kasonde sọ fun BBC pe ileewe naa ko tii sin Matfishi, o ni awọn n gbero lati fi oogun ti ko ní jẹ kí oku rẹ bajẹ si ara ẹja naa ki awọn le maa rii wo lọ.

Ninu ọrọ tiẹ, Aarẹ Lungu ṣe ayalo ọrọ ti ajaja ominira ilẹ India, Mahatma Gandhi sọ pe ilọsiwaju ati igoke agba orile-ede kankan da lori iha to kọ si awọn ẹranko rẹ.

Aarẹ Zambia ni titi laelae lorilẹ ede naa yoo maa ṣe iranti Matfishi to lọ.

Ẹwẹ, olori ẹgbẹ alatako ni Zambia, Hakainde Hichilema naa kẹdun pẹlu fasiti Copperbelt lori iku Matfishi.