Suspected ritual killer: Ọwọ́ tẹ afurasí olóògùn owó tó fẹ́ gé ọmú obìnrin nílé ìtura

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra ti tẹ ọkunrin afurasi kan to fẹ ge ọmu obinrin kan nile ituru ni ijọba ibilẹ Orumba nipinlẹ̀ Anambra.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Anambra, Haruna Mohammed, to fidi ọrọ naa mulẹ ṣalaye pe kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ naa ti ni ki ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si ọrọ ọdaran bẹrẹ iwadii kikun lọri iṣẹlẹ naa.

Mohammed sọ fawọn akọroyin pe ọkunrin kan to wa nile itura ọhun, Ogbonna Nwankwo lo ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo iṣẹlẹ naa.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ni afurasi ọhun gbiyanju lati pa obinrin naa ninu iyara ti wọn jọ wa lẹyin to gun un lọbẹ ni ikun.

''O gbiyanju lati ge ọmu apa ọtun obinrin naa eyi ti ọpọ gbagbọ pe o fẹ fi ṣe oogun ni, ṣugbọn aṣiri tu lẹyin tawọn to wa nile itura naa gbọ ariwo obinrin ọhun lati inu yara,'' agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye.

Ariwo obinrin yii ni oludari ile itura naa gbọ ki awọn agbofinro to mu un.

Awọn ọlọpaa naa lo gbe obinrin ọhun ti apa wa lara rẹ lọ si ile iwosan fun itọju niluu Nnewi.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa gbe afurasi afiniṣowo naa lọ si ile iwosan lẹyin tawọn eeyan ti lu u ni alubami.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ri ọbẹ nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.