Ikoyi Ile Farmers Herders Clash: Àwọn àgbẹ̀ Ikoyi Ile kérora síjọba ìpínlẹ̀ Oyo!

Awọn agbẹ atawọn olugbe ilu Ikoyi Ile ni ijọba ibil Orire, ipinlẹ Oyo ti ni awọn yoo papa dide iranwọ fun ara awọn ni bi ijọba ipinlẹ Oyo ba kọ lati ṣe iṣẹ didaabo bo awọn.

Wọn figbe yii ta si ijọba latari bi wọn ṣe ni awọn daran daran n dun mọhuru mọhuru mọ wọn ninu ilu wọn.

Awọn agbẹ naa ke gbajare pe pẹlu bi wọn ṣe pa ọkan lara wọn, ti wọn fipa ba awọn ọmọ wẹwẹ wọn lopọ ti wọn si ba oko wọn jẹ, sibẹ sibẹ, awọn daran daran yii ṣi n da ilu awọn laamu eyi to si n gba orun loju wọn.

Akọwe ẹgbẹ awọn agbẹ Idera, Oloye Oyekola Joseph jẹ ko di mimọ pe gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii n kọ awọn lominu lati bii ọdun mẹjọ sẹyin to si n ke si ijọba pe ki wọn tete da si ọrọ naa ko to di nkan mii.

Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ṣugbọn ta o lee fi aworan rẹ sinu iroyin yii tori o buru jai, wọn fẹsun kan pe "awọn daran daran ge ọwọ ọkan lara wọn ti wọn si tun ba oko wa jẹ, agbẹ kan ni wọn ṣa oun ni ada lori, awọn mii fara pa koda wọn fipa ba awọ́n ọmọde wa meji lo pọ".

Awọn agbẹ figbe ta pe wọn ko tii dẹkun kikọlu oko awọn, o ni awọn si ti bẹ wọn tititi ti wọn ko gbọ.

Ẹwẹ, nigba ti a kan si ileeṣẹ Ọlọpaa ati Onikoyi ti Ikoyi Ile, Oba Abdul-Yekeen Atilola Oladipupo ko tii f fesi si ọrọ yii to si sọ fun akọroyin BBC pe oun yoo kan si wọn bo ba ya.

Ilu Ikoyi-Ile jẹ ilu iṣẹmbaye kan ni ijọba ibilẹ Orire ni ipinlẹ Oyo eyi ti ilu to fẹẹ to ẹẹdẹgbẹrin yii ka bii ilu Olode-Elelu, Animashaun, Obamo, Igboayin, Laomi. ati bẹẹ lọ.