You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Umai Emery: Villarael yan akọ́nimọ̀ọ́gbá Arsenal tẹ́lẹ̀, Emery gẹ́gẹ́ bí akọ́nimọ̀ọ́gbá rẹ̀ tuntun
Unai Emery, akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal tẹlẹ ni wọn ti yan gẹgẹ bi akọnimọọgba Villareal fun ọdun mẹta.
Emery n gba iṣẹ lọwọ Javi Calleja to fi ẹgbẹ agbabọọlu naa silẹ pẹlupẹlu bi wọn ṣe ṣe ipo karun un lori atẹ liigi Spanish Liga, to si fihan pe wọn yoo lanfani lati kopa ninu idije Liigi Europa ni saa to n bọ.
Ṣẹ ẹkọ ẹlẹkọ kuku ni ẹgba ẹlẹgba ni Yoruba maa n wi
Ni oṣu kọkanla ọdun 2019 ni awọn alaṣẹ Arsenal gba iṣẹ lọwọ rẹ lẹyin to lo ọdun kan abọ gẹgẹ bii akọnimọọgba nibẹ.
Ki o to lọ si Arsenal, Unai Emery ti kọkọ ṣakoso ikọ Sevilla ati Valencia lorilẹede Spain.
Bakan naa lo tun ṣakoso ẹgbẹ agbabọọlu Paris Saint Germain lorilẹede France.
Emery gba iṣẹ lọwọ Arsene Wenger loṣu karun un ọdun 2018 lẹyin to gba ife ẹyẹ Europa mẹta tẹlera pẹlu Sevilla ati ife ẹyẹ liigi ilẹ France pẹlu PSG.