Oniru of Iru land: Onírù tuntun Oba Abdulwasiu Gbolahan Lawal gba ọ̀pá àṣẹ

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Oniru ti Iru nipinlẹ Eko, Oba Abdulwasiu Omogbolahan Lawal, Abisogun ll ti gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bi Oniru ikẹẹdogun.

Ko tii ju ọjọ mẹta lọ ti awọn afọbajẹ atawọn agbaagba ilu Iru yan an laarin awọn arẹmọ ọba to n du itẹ naa.

Lọjọ keje oṣu kẹfa ọdun 2020 ni gomina Babajide Sanwo-Olu gbe ọpa aṣẹ le e lọwọ gẹgẹ bii Oniru kẹẹdogun ti ilu Iru nipinlẹ Eko.

Gomina gba Oniru tuntun nimọran lati jẹ ki alafia tẹsiwaju ni ilu naa.

Sanwo-Olu ni pẹlu Ọlọlajulọ Ọba Abdulwasiu Ọmọgbọlahan ati Olori rẹ ni ko si ani ani, ọjọ iwaju ilu Iru yoo dara o si nireti at pe gigun ori itẹ Oniru tuntun yii yoo jẹ ibẹrẹ irinajo lọ sinu ọjọ iwaju naa.''

O ṣapejuwe ipo ọba gẹgẹ bi ibi akọkọ ninu ijọba o si ni yoo maa jẹ ọna si ibi nkan ini Naijiria ni gbogbo igba.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọdun to kọja ni ipo Oniru ṣofo nigba ti Oniru ikẹrinla, Ọba Idowu Oniru filẹ bora bi aṣọ.