Amotekun kò le ṣe èso rere nílẹ̀ Yorùbá àyàfi ni Èkó nìkan - Alao Akala

Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Oyo, Ọtunba Adebayo Alao Akala ti woye pe yoo nira fun ikọ alaabo Amotekun lati ṣe aseyọri ni awọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba.

Alao Akala, ẹni to sisọ loju ọrọ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ tun fikun pe ipinlẹ Eko ni Amotekun ti lee ṣe aseyọri to yẹ.

Akala ni ko boju mu rara bi awọn gomina yoku nilẹ kaaro oojiire ṣe fi awọn ajagunfẹyinti ṣe olori ikọ alaabo Amotekun ni Ipinlẹ koowa wọn.

Gomina tẹlẹ naa, to fẹyinti bii igbakeji kọmisana lẹnu iṣẹ ọlọpaa tun ni, Ipinlẹ Eko nikan to fi ọga ọlọpaa to ti fẹyin ti nikan lo ṣee ṣe ki ikọ alaabo rẹ yege.

Alao Akala, to n palẹ mọ fun ayẹyẹ aadọrin ọdun rẹ loke eepẹ salaye pe awọn osisẹ ọlọpaa nikan lo le mu ki ikọ alaabo naa yege.

"Ojuse awọn ọlọpaa ni lati pese eto aabo laarin ilu, ojuse awọn ọmọ ologun ni lati ja ogun, ti ologun si maa n ri ara rẹ bii ọga fun ọlọpaa, bi wọn ba wa fi ologun ṣe olori ikọ Amotekun nipinlẹ kan, wọn ko yan ẹni to tọ lati dari ikọ alaabo bẹẹ."

"Ajagunfẹyinti to ba n dari ikọ alaabo nipinlẹ kan, ko ni fẹ tẹriba labẹ kọmisana ọlọpaa to wa nipinlẹ bẹẹ, ti yoo si maa lo iwa ipa, bawo wa ni alaafia yoo ṣe wá, ọlọpaa nikan si tun lo le ba ọdaran ṣe ẹjọ."