Coronavirus: Bàyíì ní àwọn ọmọbìnrin Afghanistan ṣe fi èròjà ara ọkọ ṣe fẹntilátọ

Awọn ọmọbinrin ikọ to n se robọti ni Afghanistan ti doju isẹ wọn kọ́ awọn to ni Coronavirus

Ọhun to ku ti wọn n se bayi ni pe wọn n fi eroja ọkọ se fẹnitilatọ, to jẹ ẹrọ to n mu eemi ja geere sii olowopọọku.

Lọdun 2017 ni wọn di ilumọọka nigba ti wọn gba ami ẹyẹlati lọ kopa ninu idije agbaye kan ni Amẹrika.

Ni bayi, wọn fi gbogbo ara sisẹ la ti le pari fẹntilatọ olowo pọọku yi ki osu karun un to kasẹ nilẹ

Lorile-ede Afghanistan ti ogun ti se akoba fọpọ ọdun, wọn ko ni ju irinwo fẹntilatọ fawọn eeyan to to miliọnu mejidinlogoji le diẹ

Eeyan ẹgbẹrun meje le lo ti ko arun naa ti eeyan mejidinlọgọsan si ti tọwọ rẹ dero ọrun.

Ọkan lara awọn ọmọbinrin naa ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun mẹrinla si mẹtadinlogun sọ pe '

'O se pataki ki a sa ipa tiwa naa lori ajakalẹ aarun Covid 19, koda bo ba se eeyan kan la le doola ẹmi rẹ pẹlu igbiyanju wa''

Agbegbe Herat nibi ti eeyan akọkọ ti safihan arun Covid 19 ni ilẹ ọhun lawọn ọmọbinrin yi ti wa.

Eronja ara ọkọ aloku Toyota Corolla ati eronja seeni ọkọ alupupu Honda kan ni wọn fi se fẹntilatọ wọn.

Wọn sọ pe fẹntilatọ awọn yoo mu ki ara tu awọn ti ko ba le mi daadaa lawọn aaye ibi ti ojulowo fẹntilatọ ko ba si.

Balogun ikọ awọn obinrin yi, Somaya Faruqi ni '' Ori mi wu lati wa lara awọn ikọ to n se ohun to n se iranwọ fawọn osisẹ ilera wa. Awokọse nla ni wọn jẹ fun wa lasiko yi''

Jakejado agbaye ni ọwọngogo fẹntilatọ ti jẹ ipenija.

Pẹlu iye owo ti wọn n ta wọn, bi ẹgbẹrun lọna ọgbọn dọla si ẹgbẹrun lọna aadọta dọla, pupọ orile-ede agbaye ti ko ri taje se ni ipa wọn ko ka rira awọn fẹntilatọ yi.

Sugbọn sa, awọn ọmọbinrin wọnyi lawọn yoo se fẹntilatọ tawọn niye owo ti ko to ẹgbẹta dọla lẹyọ kọọkan.

Bayi ti wọn ti ti awọn ile itaja pa ni Herat, ipenija tawọn ọmọbinrin yi ni ni wi pe wọn ko le jade lati lọ ra awọn eroja ti wọn yoo lo lati fi se fẹntilatọ wọn.