Coronavirus: Ilé ijó Fẹla Anikulapo, New Africa Shrine gbé ìlẹ̀kùn rẹ̀ tì pa nítorí àrùn Coronavirus

Ni bayii ti olukuluku ileeṣẹ, awujọ ati orilẹede n gbe igbesẹ gbogbo lati dena itankalẹ arun coronavirus, ile ijo ogbontagi olorin ni Fẹla Anikulapo kuti ti gbogbo aye mọ si New Africa Shrine ti gbe ile ijo naa tipa.

Awọn alaṣẹ ile ijo naa ṣalaye pe awọn gbe igbesẹ ọhun lati dena itankalẹ arun ọhun ni nitori pe agbo ti ọpọlọpọ eeyan lati origun mẹrẹẹrin agbaye ti n pade ni.

Ile ijo naa ni oun yoo tubọ maa bẹju wo bi nnkan ba ṣe n lọ si lori arun naa ki wọn to tun lee sọ igba ti faaji yoo pada bẹrẹ nibẹ.

Coronavirus: Ọmọ ìkókó kan wà lára àwọn márùn ún míràn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kó àrùn coronavirus lórílẹ̀èdè Nàìjíríà

Minisita feto ilera lorilẹede Naijiria, Dokita Osagie Ehanire ti fi soju gbangba pe ọmọ ikoko kan wa lara awọn eeyan marun un ti wọn ṣẹṣẹ ri wi pe o ni arun Coronavirus lorilẹede Naijiria.

Minisita feto ilera ṣalaye pe, mẹrin ninu awọn eeyan marun un naa ni wọn jẹ ọmọ Naijiria ti ọmọ ikoko naa si jẹ ọkan lara wọn.

O fi kun un pe ọmọ orilẹede Amẹrika ni eeyan kan to ku ninu wọn ati pe kii ṣe ọkọ ofurufu loun ba wọ orilẹede Naijiria ni tirẹ.

O ṣalaye siwaju sii pe gbogbo awọn eeyan to ba ṣẹṣẹ n wọ orilẹede Naijiria lati oke okun gbọdọ fi ara wọn si igbele ọlọjọ mẹrinla, koda bi ohunkohun ko ba ṣe wọn lasiko ti wọn wọ orilẹede Naijiria.

Coronavirus: Ìjọba àpapọ̀ kéde èèyàn márùn ún míràn tó ní àrùn Coronavirus lorilẹ̀ede Naijiria

Ijọba apapọ ti kede eeyan marun miran pẹlu arun Coronavirus lorilẹede Naijiria.

Eleyi ti sọ iye awọn eeyan to ko aarun naa di mẹjọ.

Minisita feto ilera to kede eyii. O ni awọn maraarun naa ni wọn ti rinrinajo lọ sorilẹede Amẹrika ati ilẹ Gẹẹsi laipẹ yii.

Coronavirus: Nítorí àrùn Coronavirus ìjọba àpapọ̀ ní káwọn arìnrìnàjò láti orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà, Gẹ̀ẹ́sì, Faransé àtorilẹ̀èdè mọ́kànlá míràn o gbélé wọn

Gẹgẹ bii ara eto lati tete wawọ ọwọja arun Coronavirus wọlẹ, ijọba orilẹede Naijiria ti gbẹsẹle irinajo lati awọn orilẹede Mẹtala kan wọ orilẹede Naijiria.

Ohun ti eyi tumọ si ni pe ko si awọn arinrinajo lati awọn orilẹede mẹtala naa to gbọdọ wọ orilẹede Naijiria.

Awọn orilẹede ti ọrọ kan naa ni orilẹede China, Italy, Iran, South Korea, Spain, Japan, Faranse, Germany, Amẹrika, Norway, ilẹ Gẹẹsi, Netherlands ati orilẹede Switzerland.

Ijọba apapọ ni awọn gbe igbesẹ yii lori awọn orilẹede to jẹ wi pe iye awọn eeyan to ti fara ko arun Coronavirus ti ju ẹgbẹrun kan lọ.

Alaga igbimọ amuṣẹya ti ijọba apapọ gbe kalẹ lori pipalẹmọ arun Coronavirus kuro lorilẹede Naijiria (Presidential Task Force on COVlD-19) ṣalaye fawọn oniroyin ninu Abuja pe ayẹwo to munadoko yoo maa waye fun gbogbo awọn eeyan to ba wọ orilẹede Naijiria lẹyin abẹwo sawọn orilẹede wọnyii; ti wọn yoo si fi wọn sinu ahamọ iyasọtọ ati ayẹwo fun ọjọ mẹrinla.

Bakan naa ni ijọba apapọ tun ṣalaye pe aṣẹ yii lo bẹrẹ si ni fi ẹsẹ mulẹ bẹrẹ lati ọjọ Satide, ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹta ọdun 2020.

Bakan naa ni wọn tun fi idi rẹ mulẹ pe, lasiko ti aṣẹ yii yoo fi fidi mulẹ, ko ni si aye a n fun ẹnikẹni ni iwe aṣẹ iwọlu-gbelu ti a mọ si visa.