You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Premier league: Àdúra Arsenal gbà, Watford ja Liverpool bọ́ ní ìlépa àkọsílẹ̀ 'Invincibles' pẹ̀lú góòlù mẹ́ta
Iyalẹnu nla lo jẹ fun ọpọlọpọ onwoye ere bọọlu lagbaye, paapaajulọ awọn ololufẹ idije liigi ilẹ Gẹẹsi loni nigba ti ifẹsẹwọnsẹ laarin Watford and Liverpool pari loni.
Esi ifẹsẹwọnsẹ ọhun kii ṣe ohun ti ọpọ lero ṣugbọn lẹyin o rẹyin goolu mẹta si odo ni Watford fi na Liverpool.
Igba akọkọ niyi ti Liverpool yoo maa fidirẹmi ni idije liigi ilẹ gẹẹsi lati ọjọ mejilelogun o le irinwo sẹyin
Ọpọ lo ti n woye pe Liverpool yoo pa akọsilẹ ti ẹgbẹ agbabọọlu Arsena fi lelẹ ni saa liigi ọdun 2004 si 2005 nigba ti wọn gba ifẹsẹwọnsẹ mọkandinlaadọta lai fidirẹmi.
Ifẹsẹwọnsẹ mẹrinlelogoji ni Liverpool ti gba laifidirẹmi ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Watford loni eyi to fihan pe wọn yoo ni lati duro fun saa liigi miran ki wọn to lee pa akọsilẹ naa rẹ.
Yatọ si eyi, ifẹsẹwọnsẹ mejidinlogun ni Liverpool ti gba ti wọn si ti bori ni ṣisẹntẹle lẹyin ti wọn ti ta ọmi pẹlu Manchester city.
Bakan naa, oni yi gan naa lo pe ọdun kan o din ọjọ mẹta ti Liverpool ti gba ifẹsẹwọnsẹ liigi lai gba goolu wọle.
Ismaila Sarr lo kọkọ gba goolu wọle ni igba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹrinlelaadọta ati ọgọta, ki Troy Deeney to fọba lee ni igba ti o wọ iṣẹju kejilelaadọrin