You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Anthony Joshua: Lẹ́yìn ìjà rẹ̀ pẹ̀lú Luiz, Anthony Joshua bẹ Ọba ìlú rẹ̀, Àkárìgbò wò
Ṣe awọn agba bọ wọn ni ọmọ ale ni fi ọwọ osi juwe ile baba rẹ.
Gbajugbaja akanṣẹ lagbaye, Anthony Joshua bẹ ile wo lọjọru. Taara ta ilu rẹ ni Ṣagamu lo mori le, nibẹ lo si ti ṣe baba kẹẹ pẹ sawọn ọbalaye ati oriade gbogbo to wa nilu naa.
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Adìyẹ Broiler ń fa àìsàn Coronavirus?
- Anthony Joshua gba nọ́mbà ìdánimọ̀ NIN, àwọn ọmọ Nàìjíríà kan kérora lórí ètò náà
- Coronavirus: Ó dá mi lójú pé ìwá ìbàjẹ́ ló fa àrùn yìí - Ọ̀gá àgbá EFCC
- Ibà Lassa wọ ìpínlẹ̀ Èkó!
- Àwọn ọba tó wà lábẹ́ mi ń talẹ̀ nítàkutà- Oluwo
- Oyè Ibadan kò sí fún títà - Otun Olubadan, Lekan Balogun
Eyi ni igba akọkọ ti Anthony Joshua yoo maa yọju si orilẹede Naijiria lẹyin to gba igbanu ẹyẹ agbaye rẹ, WBA, WBO, IBF ati IBO pada lọwọ Andy Ruiz.
Ọmọ orilẹede Mexico naa si lo gba ami ẹyẹ ọhun dani fun bi oṣu diẹ, nibi ija wọn to waye ni gbagede Diriyah Arena lorilẹede Saudi Arabia.
Ọkẹ aimoye awọn ololufẹ rẹ ni wọn rọgba yii ka lasiko to fi lọ ki Alafin Ẹlẹpẹ ati Akarigbo ti ilẹ Rẹmọ ni aafin wọn.
Lẹyin to foribalẹ fawọn ọba alade naa tan, ni Anthony Joshua wa ya fọto pẹlu awọn ololufẹ rẹ ti wọn wa foju gaanni rẹ.
Ariwo 'ibi ni ile rẹ kii ṣe ilẹ Gẹẹsi' ni ọpọlọpọ awọn eeyan to tu sita wa wo agba ọjẹ akanṣẹ naa n pa, bi gbogbo wọn ṣe n da giiri lati baa ya fọto, ti wọn si tun wọ tọọ lẹyin lati aafin Elepe lọ si aafin Kabiyesi Akarigbo ti ilu Rẹmọ.