Balogun Fire: Ilé ìtajà alájà mẹ́rin ni iná náà ti kọ́kọ́ sẹyọ

Ọ̀ga àgbà àjọ LASEMA Femi Osanyitolu, sàlàye pe ni kété ti àwọn de ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni àwọn ti ri pé ilé alájà mẹrin kan ni ìnà náà ti bẹ̀rẹ̀.

O sálàyé pé ǹkan to fa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni bi àwọn ènìyàn ṣe n ko epo pamọ lanà ti kò dára lo ṣẹ iná yẹ

Fidio bi ina se jo ọja Balogun ree:

O ni láti ibẹ̀ lo ti fò mọ ilé méje míràn sùgbọ́n àjọ LASEMA ní àwọn ti ń kápa rẹ ti àwọn si ti wó ilé méjé ti iṣẹ̀lẹ̀ náà de bá

Gbogbàwọn àjọ to yẹ lo ti wà nilẹ̀, ti Osanyitolu si ti rọ gbogbo àwọn ènìyàn láti lo fi ọkàn wọ́n

Ó ṣeéṣe kó jẹ́ ọyẹ́ tó ń mú lásìkò yìí ló fa ìjàmbá iná lọ́jà Balogun - LASEMA

Isẹlẹ ina to n jo lemọlemọ lẹnu lọọlọ yii tun ti na ọwọja rẹ de gbajugbaja ọja Balogun nilu Eko, to si nawọ gan ibudo itaja mẹrin ọtọọtọ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ akọtun isẹlẹ naa, oludari ajọ to n risi isẹlẹ pajawiri nipnlẹ Eko, LASEMA, Femi Oke Ọsanyintolu, salaye pe oun ko tii le sọ ohun to se okunfa ijamba ina ọhun.

Ọsanyintolu ni o seese ko jẹ asiko ọyẹ taa wa yii lo mu ki isẹlẹ ina ọhun waye, gẹgẹ bo se n sẹlẹ kaakiri agbegbe wa lẹnu lọọlọ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

LASEMA ni opopona Martins ti ina ti sọ nijooni, naa tun ni ijamba ina mii ti n waye lọwọlọwọ bayii, ti awọn osisẹ ajọ naa ati awọn panapana si ti de sibi isẹlẹ ọhun lati tete bomi pa ina naa ki ọwọja rẹ to kọja aala.

O fikun pe ko sẹni to lee se odiwọn ọsẹ ti ina naa ti se nitori pe o si n jo lọwọ, amọ ni kete ti ọwọja rẹ ba ti lọ silẹ, ni awọn yoo fi ikede sita lati salaye lẹkunrẹrẹ nipa isẹlẹ naa.

Bẹẹ ba gbagbe, igba meji ọtọọtọ ni awọn ile itaja jona ni ọja Balogun lọdun to kọja, ti ọkẹ aimọye dukia si baana.

Ọ́pọ awọn ontaja si la ri ti wọn n wọ inu ina lati ko ọja wọn jade ko maa baa jona, eyi to lewu pupọ.

Ìròyìn Yàjóyàjó - Iná sọ nílé ìtajà mẹ́rin lọ́jà Balogun l'Eko

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé ile itaja mẹrin ni ọja Balogun lo n jona lọwọ lọwọ bayii.

Bi o tilẹ jẹ pe ko si ẹni to tii lee salaye ohun to fa ina ọhun, sibẹ a ko tii kofiri awọn osisẹ panapana nibẹ́.

Ko si si ẹni to lee sọ iye dukia to jona nitori ina ọhun si n jo lọwọ.

A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.