Insecurity: Ilé aṣojú-ṣòfin ní ìpànìyàn, ìjínigbé, ìdigunjalè, ìgbéṣùnmọ̀ọ́mí ń peléke ni

Ile Igbimọ Asofin apapọ lorilẹede Naijiria ti pe fun eto pajawiri lati koju eto aabo to n dẹnukọlẹ si lorilẹede Naijiria lojoojumọ.

Ile Igbimọ Asofin apapọ naa sọ eyi lasiko ijoko ile lẹyin ti wọn de lati isinmi ọlọsẹ marun un ni ọjọ Iṣẹgun.

Ile igbimọ asoju-sofin fi ikilọ lede lori iṣekupani, ijinigbe, ole jija ati igbesunmọmi kaakiri orilẹede Naijiria, pẹlu adehun pe wọn gbọdọ wa ọna abayọ ni kiakia.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ wọn, ẹgbẹ oṣelu PDP fidi ẹ mulẹ pe, iṣekupani ni ipinlẹ Plateau ti peleke si, ti wọn si fẹsun kan ijọba apapọ pe wọn ko ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ ni iṣẹkupani to n waye ohun.

Ile asofin agba wa parọwa lati gbe ọrọ ọlọpaa abẹle wo lati gbogun ti eto aabo to dẹnukọlẹ.

Alaga ile lori eto ibanisoro, Benjamin Kalu naa sọ wi pe, ipeleke ti ba iṣekupani ni agbeegbe Ila-oorun apa ariwa Niajiria, to si n beere ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa n ṣe lati gbogun ti eto aabo to dẹnukọlẹ naa.

Kalu fikun pe, ẹtọ araalu ni pe ki ijọba ti wọn dibo fun pese aabo to peye fun ẹmi ati dukia awọn araalu, ki awọn eniyan ma ba a ma gbe ninu ifoya.

Iwadii fihan pe, laarin osu mẹta, ipaniyan ti peleke si lagbeegbe Zamfara, Kaduna, Kastsina ati ipinlẹ Niger.

Amọ Olubadamọran fun aarẹ Muhammadu Buhari lori ọrọ iroyin, Femi Adesina fi lede wi pe, eto aabo ko dẹnukọlẹ to bi awọn eniyan ṣe n sọ to.

O ní o yẹ ki awọn eniyan ma a dupẹ lọwọ aarẹ nitori iṣẹ to ṣe lati fi opin si iṣekupani ni Naijiria.