You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ibadan High Chiefs: Àwọn Olóyè Ibadan mọ́kànlélógún tó ń pe ara wọn lọ́ba ń fi ẹ̀wọ̀n run imú
Ọrọ ko tii tan lori awọn oloye mọkanlelogun ti ile ẹjọ sọ pe ki wọn lọ rọọkun nile niluu Ibadan.
Kọmiṣọnna eto idajọ tẹlẹ ri nipinlẹ Oyo, Ọgbẹni Michael Lana lo ṣe ikilọ fun wọn pe ki wọn ye pe ara wọn ni ọba kaakiri, bi bẹẹ kọ, wọn n fi ẹwọn run imu ni.
Ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni Lana fi sita lọjọ Aje, o sọ wi pe bi awọn oloye naa ti n pe ara wọn ti wọn si n gbe ara wọn gẹgẹ bi ọba lodi si aṣẹ ile ẹjọ.
''Igbesẹ ijọba ana nipinlẹ Oyo to fun awọn oloye mọkanlelogun lati maa de ade ilẹkẹ, ati lati maa pe ara wọn ni ọba lodi si ofin,'' Ọgbẹni Lana lo woye bẹẹ.
O ṣalaye siwaju sii pe idajọ ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo to waye lọjọ kọkandinlogun oṣu kọkanla ọdun 2019 ti gbe igbesẹ ijọba ana lori awọn oloye Ibadan sẹgbẹ kan.
Ọgbẹni Lana sọ pe iyanlẹnu lo jẹ pe awọn kan si tun n wọ ade ilẹkẹ ti wọn si n pe ara wọn ni ọba ilu Ibadan.
O ni ijọba koni bẹṣubẹgba lati gbe igbesẹ lori bi awọn oloye mọkanlelogun naa ṣe n pe ara wọn ni ọba kaakiri.
Ọgbẹni Lana wa kepe Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Oyo pe ko paṣẹ fawọn agbofinro lati fi ọwọ ofin mu ẹnikẹni ninu awọn oloye naa to ba n pe ara rẹ lọba.