You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Buhari mú ayé dẹrun fún àwọn ọmọ Nàìjíríà ju àwọn ìjọba àtẹ̀yìnwá lọ- Lai Mohammed
Minisita eto ibanisọrọ ati iroyin, Lai Mohammed ti gboriyin fun ijọba aarẹ Muhammadu Buhari lẹyin to ni ijọba ọhun pese awọn ohun amayedẹrun fun awọn ọmọ Naijiria.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ Naijiria kan koro oju si ina ijọba ti ko ṣe dede ati ọna to ti mẹhẹ, ọgbẹni Lai sọ pe ijọba Buhari pegede bo ṣe pese awọn ohun amayedẹrun.
O ni ijọba Buhari pegede ju gbogbo ijọba to ti ṣaaju lọ ni pipese awọn ohun amayedẹrun fun awọn Naijiria.
Agbẹnusọ ijọba lo sọ ọrọ yii nibi ifọrọwerọ pẹlu awọn oniroyin, nibi to ti n ṣe alakalẹ aṣeyọri ijọba Buhari lọdun 2019.
Lai sọ pe "Bi a ṣe n sọrọ yii, awọn ohun amayedẹrun bii opopona, ọna oju irin, ina mọnamọna, ati awọn ouhn miran ni ijọba yii n ṣe lọwọ."
O tẹsiwaju pe "Ko tii si ijọba kankan to gunle iru iṣe bayii, papa julọ ni igabti ọrọ aje dẹnu kọlẹ."
- Ẹni orí yọ, ó dilé! Agbébọn pààyàn méjì ní ṣọ́ọ̀ṣì, olùjọ́sìn yìnbọn p'òun náà
- ‘Ìjọba àpàpọ̀ gbọdọ̀ tọrọ ìdárìjì lọ́wọ́ Sowore, Dasuki’
- Marlian, òfégè ìgbéyàwó Buhari, Fatoyinbo àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá tó mi ìgboro tìtì ní 2019
- Bukola Saraki fi 'Gbas Gbos' ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí 'ilẹ̀ bàbá rẹ̀' tí ìjọba Kwara gbà padà
Ọgbẹni Lai ni ko si ijọba kankan ti yoo la oju rẹ silẹ ki ilu bajẹ mọọ lori.
O ni owo ti ijọba apapọ n ya jẹ lati fi pese awọn amayedẹrun mii ti yoo mu ki ọrọ aje orilẹ-ede Naijiria gberu sii.