You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Drunk driving: Mu pàrágá wakọ̀ l'Oyo, kóo kó sí gbaga ìjọba
Omi tuntun ti ru, ẹja tuntun ti wọ ọ ni ipinlẹ Oyo. Awakọ mẹẹdọgbọn ni ọwọ ofin ti tẹ nipinlẹ naa lori ẹsun pe wọn n muti nigba ti wọn tun n wa ọkọ.
Kọmiṣọnna nipinlẹ naa lasiko ọhun, ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe igbesẹ yii yoo jẹ ẹkọ fawọn awakọ mii ti wọn ba tun fẹ hu iru iwa bẹẹ.
Ajọ to n ri si idari ọkọ ni ipinlẹ Oyo, OYRTMA mu awọn awakọ naa pẹlu iranlọwọ ẹrọ igbalode to le ṣafihan bi eeyan ba mu ọti.
- Ṣé oyún ní Aisha Buhari ni àbí àìsàn jẹjẹrẹ tàbí kí ló fa ẹ̀jọ́ lórí ikún aya Aàrẹ Buhari?
- Damola Olatunji fojú balé ẹjọ́, wọ́n ní ó dúnkookò mọ́ ọlọ́pàá, wọ́n tún ka àwọn ẹ̀sùn míì si lẹ́sẹ̀
- Wo orílẹ́èdè tó fẹ́ fi òfin de sìgá mímú fún ìran ọmọ wọn tó ń bọ̀
- Ìdí rèé tí Buhari fi kọ̀ láti buwọ́lu àbá àtúnṣe ètò ìdìbò Nàìjíríà
- Ṣé oyún ní Aisha Buhari ni àbí àìsàn jẹjẹrẹ tàbí kí ló fa ẹ̀jọ́ lórí ikún aya Aàrẹ Buhari?
O sọ pe gbogbo awọn awakọ mẹẹdọgbọn naa ni yoo foju ba ile ẹjọ.
Kọmiṣọnna ni ile ẹjọ si ni yoo sọ pato ijiya to tọ si wọn.
O tun fi kun ọrọ rẹ pe mimu awọn awakọ to n mu ọti kii ṣe ninu asiko pọpọsinsin nikan.
O ni eto naa yoo tẹsiwaju ninu ọdun 202i nitori ẹmi awọn eeyan ipinlẹ jẹ ijọba Gomina Ṣeyi Makinde logun.
Ẹwẹ, alaga OYRTMA ṣalaye pe igbesẹ ajọ wọn lati mu awọn ọmuti awakọ wa ni ibamu pẹlu iṣẹ ajọ naa lati dẹkun ijamba ọkọ tawọn ọmuti awakọ n ṣe okunfa rẹ nipinlẹ Oyo.
O fi kun ọrọ rẹ pe ni opopona Ring-Road, Iwo-Road, ati Moniya si Ogbomoso ni wọn ti mu awọn awakọ ọhun.