Nàìjíríà ni orílẹ̀-èdè kẹta tí ìkọlù ìgbésùnmọ̀mí pọ̀ sí jùlọ láàgbáyé

Abajade iwadii kan lori iwa igbesunmọmi ti kede rẹ pe Naijiria ni orilẹ-ede kẹta ti iwa igbesunmọmi ti wọpọ ju lọ lagbaye lọdun 2018.

Iwadii naa ti ajọ Development and Peace Initiative (IEP) ni ilu Sydney lorilẹ-ede Australia gbe jade ṣalaye pe ti a ba n sọrọ iwa igbesunmọmi lagbaye.

Wọn ni ọga ni kanwun lawujọ okuta ni orilẹede Afghanistan ati Irag. Lẹyin wọn lo wa kan orilẹede Naijiria ti a ba ni ki a wo iye awọn ẹmi ti o ti lọ sii.

Amọṣa, abajade iwadii naa ko ṣai tun ṣe e lalaye pe iye awọn eeyan to ku sinu ikọlu igbesunmọmi ti dinku lọdun 2019 yii si ọdun 2018 lorilẹ-ede Naijiria.

Oye ọlajingiri ni orilẹ-ede Naijiria jẹ lori igbelewọn naa nitori ipo kẹta yii kan naa ni wọn wa ni ọdun 2018.

Orilẹ-ede mẹwaa miran ni ilẹ Afirika ni wọn wa laarin ipo ogun akọkọ igbelewọn awọn orilẹ-ede ti iṣẹlẹ igbesunmọmi ti gogo julọ lagbaye.

Bakan naa ni wọn tun fihan ninu iwadii naa pe iwa igbesunmọmi ti n pọ sii lagbaye.

O fi kun un pe iṣẹlẹ igbesunmọmi ọtalelẹẹdẹgbẹta ati meji, 562 lo waye lọdun yii lorilẹ-ede Naijiria eleyi to gba ẹmi ojilelugba, 2040 ti Naijiria tun fi di ipo kẹta mu.

Lorilẹ-ede Afghanistan to wa ni ipo kinni, ojilelegbeje ati mẹta, 1443 ikọlu igbesunmọmi lo waye nibẹ ninu eyi ti ẹgbẹrun meje ati ọọdunrun o le mọkandinlọgọrin, 7379 ẹmi si dero ọrun ọsan gangan.

Iraq to ṣe ipo keji foju wina ikọlu igbesunmọmi ẹẹdẹgbẹfa ati mọkanlelọgbọn 1131 to gbẹmi ẹgbẹrun kan ati mẹrinlelaadọta, 1054 eeyan.

Abajade iwadi yii fihan pe ikọlu igbesunmọmi lorilẹ-ede Naijiria pọ ju ti orilẹ-ede Syria to wa ni ipo kẹrin pẹlu ikọlu ọtalelẹgbẹta ati meji, 662to sọ eeyan mọkanlelogoje, 131 di ero ọrun alakeji.

Ni gbogbo ilẹ Yuroopu eeyan mejilelọgọta 62 lo ba ikọlu igbesunmọmi lọ eyi si dinku si igba 200, to jẹ lọdun 2018.