You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Buhari vs Atiku: Ẹni tó bá kàwé leè di Ààrẹ, dandan kọ́ ni ìwé ẹ̀rí - Ilé ẹjọ́
Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹ-ede Naijiria ti sọ pe, Aarẹ Muhammadu Buhari yẹ lati dije sipo Aarẹ orilẹ-ede yii, lo jẹ ki oun da ẹjọ Atiku Abubakar nu.
Ile ẹjọ naa ni ofin orilẹ-ede Naijiria sọ pe ẹnikẹni to ba fẹ dije sipo Aarẹ gbọdọ kawe, o kere ju, ko lọ sile iwe girama.
O ni ohun ti ofin sọ ni pe ki ẹni naa kawe, yala o ni iwe ẹri tabi ko ni iwe ẹri.
- Wo díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ ìkẹyìn ti Alexander Akinyele fi léde kó tó papódà
- Ohun tó ṣe pàtàkì nípa Edgal Imohimi, Kọmisánà ọlọ́pàá tuntun fún ìpínlẹ̀ Ogun
- Àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ti di dandan fáwọn tó bá fẹ́ ṣèyàwó ní Nàìjíríà- Ilé aṣojú-ṣòfin
- Ìbínú ẹlẹ́wọ̀n! 'À ń lọ ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fún ẹ̀kúnwó owó oṣù ẹlẹ́wọ̀n'
Ile ẹjọ ọhun sọ pe, gẹgẹ bi ofin ṣe gbee kalẹ, ẹni ti o ba ka iwe alakọbẹrẹ, to le kọ, to si le ka ni ede Gẹẹsi le dije ninu idiibo.
Ninu idajọ naa ti adajọ agba lorilẹ-ede yii, Tanko Muhammad kọ, ti adajọ John Okoro ka sọ pe, ẹjọ ti oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar pe ko lẹsẹ nilẹ.
Lẹyin naa lo fontẹ le ẹjọ ti ile ẹjọ to n gbẹsun idibo da ṣaaju pe, Muhamadu Buhari ni ojulowo ẹni to bori ninu idi aarẹ lọdun 2019.
O tẹ siwaju pe, Aarẹ Buhari ko parọ fun ajọ INEC nipa ipele iwe to ka.
Ile ẹjọ ọhun tun ni, oludije labẹ asai ẹgbẹ PDP ko fi idi rẹ mule pe, itakun ayelujara to ti ri esi idibo naa jẹ ti ajọ eleto idibo tabi kii ṣe ti ajọ INEC
Ati pe Atiku kuna lati fidiẹ mulẹ pe aiṣe deede wa lasiko idibo naa ati pe wọn dibo kọja iye.