Helgies Bandeira: Ọ̀pọ̀ oúnjẹ Yorùbá ni à ń jẹ ni Brazil
Awọn oriṣa Brazil ló ni akara- Helgies
Adele aṣoju orilẹ-ede Brazil ni Naijiria, Helgies Bandeira gba BBC Yoruba lalejo ninu ọgba ileeṣẹ Brazil nilu Eko.
O ṣalaye kikun nipa ijọra awọn aṣa Yoruba ati ti orilẹ-ede Brazil.
Helgies ni awọn ti Brazil maa n ro pe aṣa Yoruba ni aṣa ti wọn naa ni Brazil.
O ni awọn naa n sin oriṣa bii Ogun, Ọṣun, Ọbatala, Yemoja atawọn mii.
- Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Olùdásílẹ̀ FIN
- Èèdì rèé o! Olùkọ́ fẹgba lu akẹ́kọ́ọ̀bìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá pa ní yàrá ìkàwé
- Mobolaji Johnson: Kíkọ́ Eko Bridge, wíwó ibojì òkú Ajẹlẹ àti àwọn mánigbàgbé míì tó ṣe l'Eko
- Ọmọ Nàìjíríà ló lè sọ bó yá ìdájọ́ òdodo nilé ẹjọ́ dá- Atiku Abubakar
Bakan naa ni Helgies sọrọ lori ounjẹ bii akara to jẹ tawọn oriṣa ati akarajẹ to jẹ tawọn eniyan.
Opọ ọmọ Yoruba ni wọn ko lọ si orilẹ-ede Brazil nipasẹ owo ẹru laye atijọ ni eyi ti ọpọ si ti di ero Brazil lati atọmọdọmọ wọn.