Aisha Buhari: Afenifere, PDP, ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni ni àgbà Buhari kò tolé

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọrọ ọhun bẹrẹ bii awẹwa nigba ti Fatima ọmọ Mamman Daura, gbe fidio kan sita, ninu eyi ti ohun iyawo aarẹ, Aisha Buhari ti n sọrọ lohun rara.

Esi Aisha Buhari ati Fatima Daura gan funrarẹ lo tubọ fina mọ ọrọ naa, eyi to wa di ohun ti gbogbo awọn ọmọ Naijiria n gba bi ẹni n gba igba ọti, lati bii ọjọ diẹ sẹyin.

Bakan naa, fidio miran tun jade lẹyin eyi nibiti aya aarẹ, Aisha naa tun ti n ba awọn akọroyin sọrọ pe, lootọ oun lo wa ninu fidio ti Fatima Daura gbe sita naa.

Fidio naa si lo fi oju rẹ han sita pe, baba Fatima, iyẹn Mamman Daura to jẹ bi aburo fun aarẹ, ti ko gbogbo awọn eeyan to wa ni ile aarẹ, titi kan awọn agbofinro, ni papa mọra.

Oniruuru awọn eeyan ati ẹlẹgbẹjẹgbẹ lorilẹede Naijiria lo ti sọrọ lori ọrọ yii, ti wọn si ti fi iha ti wọn kọ si bi nnkan ṣe n lọ laarin mọlẹbi akọkọ lorilẹede Naijiria han.

Ileeṣẹ aarẹ lorilẹede Naijiria pẹlu ti da si ọrọ naa gẹgẹ bi awọn iwe iroyin abẹle kan ti gbe e sita.

Loju opo twitter lawọn ọmọ Naijiria ti tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ sita, nibi ti wọn ti n fi ẹhonu wọn han lori ọrọ naa.

Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ti wa n beere pe, bi ọrọ ti ṣe ri yii, o n fẹ amojuto ati apero nitori ko sẹni fẹ mọ mọ bayii, boya Buhari ni aarẹ tabi Mamman Daura.

Bakan naa ni awọn miran ni bi o ti ṣe yẹ ko ri naa lo rii yẹn, nitori nigba ti ebi n pa igun aarẹ Buhari, awodi Mamman Daura ba ra.

Ẹwẹ, ẹgbẹ Yoruba, Afẹnifẹre pẹlu ti ke si Aarẹ Buhari pe ko ṣe iṣe agba to n tole nigba yiyanju ọrọ naa ni kiakia.