You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sex for Grades: Fídíò oní wákàtí kan BBC tún fojú olùkọ́ méjì míì hàn lórí ìwà ìbàjẹ́
Ọjọ nla ni ọjọ Aje, ọjọ Keje osu Kẹwa ọdun 2019 nigba ti ileesẹ BBC gbe fidio kan sita eyi to da lori awọn akẹkọ fasiti meji ti wọn n beere fun ibalopọ lọna aitọ lọwọ awọn akẹkọọ wọn.
Akori fidio naa lo pe ni 'Ibalopọ fun maaki' tawọn oloyinbo n pe ni 'Sex for Grades', eyi to ti n mu ki oju awọn opo itakun agbaye gbona jain-jain.
Ẹkunrẹrẹ fidio oniwakati kan ti BBC fisita nirọlẹ ọjọ Aje naa ree:
Bi o tilẹ jẹ pe fidio onisẹju mẹtala pere ni BBC kọkọ ju sori afẹfẹ nidaji ọjọ Aje naa, lawọn oju opo ikansira ẹni rẹ lori itakun agbaye, eyi ti BBC Yoruba ko gbẹyin nibẹ, amọ nigba ti yoo fi di aago meje irọlẹ ọjọ naa, ẹkunrẹrẹ fidio naa, to jẹ oniwakati kan ti gba afẹfẹ kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Fídíò rèé nípa bí Aláké tuntun ṣe ń gba ìwúre lábẹ́ Olúmọ kó tó gba adé
- Rashidi Ladọja ṣe ọjọ́ ìbí alárinrin, Ibadan mì tìtì
- Mo sọkún nípa fídíò BBC torí ó jẹ́ ìtàn tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi rí - Bisi Fayemi
- Ìdájọ́ àkọ́kọ́ kò tẹ́ mi lọ́rùn, mo tún tí gbé Seyi Makinde lọ silé ẹjọ́ - Bayo Adelabu
- Njẹ ààbo wà fún Buhari nílé aṣòfin àpapọ̀ bi yoo se gbé àbá isúna kalẹ lónìí ?
Olukọ kan lati fasiti Eko, UNILAG, Ọmọwe Boniface Igbenegbu pẹlu akẹẹgbẹ rẹ ni fasiti Ghana, Ọmọwe Paul Butakor, ni wọn foju han ninu fidio naa, amọ fidio oniwakati kan yii lo tun fi oju awọn olukọ meji miran han to n kopa ninu iwa idojutini yii lati fasiti mejeeji taa darukọ siwaju naa.
Orukọ awọn olukọ meji naa ni Ọmọwe Samuel Ọladipọ to wa ni ẹka ti wọn ti n kọ nipa ọrọ aje (Economics) ati Ọjọgbọn Ransford Gyampo, to wa ni ẹka imọ fun eto oselu lọgba fasiti Ghana , tii tun se onwoye ohun to n lọ ni awujọ.
Bawo ni Ọmọwe Samuel Ọladipọ ṣe beere fun ibalopọ lọwọ akẹkọọ?
Jẹjẹ kuku ni bilisi sun silẹ, ti Samuel Ọladipọ si lọ faa lẹsẹ, nitori jẹjẹ ni akọroyin to n sisẹ iwadi fun BBC lori fidio naa, Kiki Mordi, duro sẹnu iloro to si n reti akọroyin ti wọn dijọ wa, eyi to wa ni ọọfisi Boniface.
Sugbọn Ọladipọ ro pe akẹkọ ni Kiki, tori bo se duro, lo ba nawọ faa wọ inu ọọfisi rẹ lai mọ pe igbesẹ naa yoo ko ohun wọ inu wahala, nigba to ya ni onitọun naa parọ pe akẹkọ to n wa maaki lọdọ rẹ ni oun.
Kia lo ni ki akọroyin naa fun oun ni nọmba ẹrọ ipe rẹ, to si pe wa si ọọfisi rẹ pe ko wa gba idanilẹkọ ni igba mẹta ọtọọtọ
Kiki ni gbogbo iwa Ọladipọ si oun ni ko tọ, to si n sọ lọpọ igba fun oun pe oun dun pupọ ni ọmọbinrin
O fikun pe se ni Ọladipọ n wo igba aya oun laisẹju, eyi to fihan pe ọmu aya oun lo n wo, to si n fi ọwọ ra oun lọwọ loore koore.
Nigba to ya, Kiki ni Ọladipọ ni ki oun tẹle oun lọ si ile igbafẹ awọn agba olukọ to wa lọgba fasiti Eko, eyi to fi idi 'yara tutu', 'Cold Room', ti Boniface mẹnuba saaju ninu fidio naa mulẹ.
Ohun to n waye ni 'Cold Room' ree:
Inu yara naa sokunkun diẹ nitori ina ti wọn fi n jo ijo takasufe, taa mọ si 'Disco' ni wọn tan sibẹ, eyi ti ko ni jẹ ki oju awọn eeyan to wa nibẹ tete han si ẹlomiran
Ọpọ awọn akẹkọ obinrin lo tẹle awọn olukọ ọkunrin wa si yara tutu naa, ti wọn si n fi ọti lile lọ wọn lati mu.
Wọn n pe awọn akẹkọ obinrin naa wa sita lati jo, ti wọn si n fi ara ro wọn lara, fọwọ ra wọn ni idi, fẹnu ko wọn lẹnu tabi fi ọyan wọn sere lasiko ti wọn ba n jo.
Iriri akọroyin pẹlu Ọjọgbọn Ransford Gyampo:
Gẹgẹ bi iwadi BBC ti salaye, ilumọọka, agba olukọ ati ẹni ọwọ to maa n bu ẹnu atẹ lu ọpọ iwa aidaa lawujọ ni Ọjọgbọn Ransford Gyampo, to jẹ olukọ miran to tun foju han pe o n beere ibalopọ lọwọ akẹkọ lọna aidaa ninu fidio oniwakati kan ọdun.
Koda Gyampo ko tiẹ fi akoko sofo rara lati gbe akọroyin naa jade, o ra ọpọ ẹbun fun, to si n fi ọwọ raa lara titi de ọyan rẹ.
Pabambari ohun ti Gyampo tun se ninu fidio naa, to si ya ni lẹnu ni pe o n beere lọwọ akọroyin to dibọn bii akẹkọ naa boya wọn ti fẹnu koo lẹnu tipatipa ri.
Mo sunkún nípa fídíò BBC torí ó jẹ́ ìtàn tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi rí - Bisi Fayemi
Tun wẹ, aya gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti, Bisi Fayemi ti kún ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà to bẹnu àtẹ lú ìwà kí olùkọ́ọ̀ fásiti máá bẹeere fún ìbálòpọ̀ láti fún àkẹ́kọ̀ọ́ ní máàkì.
Èyí wáye lẹ́yìn ti ilé iṣẹ́ BBC gbé fọ́nran ìwadìí àwọn olùkọ̀ọ́ nilé ẹ̀kọ́ kan ní Nàìjíríà àti Ghana sita, ti wọn n beere ibalopọ lna aitọ lọwọ awọn akẹkọọ.
Bisi Fayemi sàlàyé pé, o jẹ́ ǹkan to bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn olùkọ̀ọ́ yiìí máa ń rò pé àwọn ni ẹ̀tọ́ si àgọ ara àwọn akẹ́kọ̀ọ́binrin wọ́n.
"Mo sunkun nítori ǹkan ti àwọn ọmọbinrin yìí ń koju jẹ́ ìtàn ayé ọ̀pọ̀ wa tó lọ ilé ìwé ni orílẹ̀-èdè yìí."
"Lásìkò ti mó kàwé ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, èmí pàápàá foju wina irú ìwà yiìí lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ mi ní fásìtì, bo tilẹ jẹ́ pé ori tún kó èmi yọ ju àwọn eyí lọ.''
"Iriri temi ko rìn jìnna sùgbọ́n kìí ṣe ìrírí to dára, kò sí ẹni ti ènìyàn le sọ fún, to bá tilẹ̀ gbìyànjú láti sọ fún ẹnikẹ́ni, wọ́n yoo ni ki o gbẹ́nu dákẹ́.
Ìyàwọ gómìnà fi kún pé, lójuna àti dẹkun ìwà ibajẹ báyìí, ìpínlẹ̀ Ekiti ti gbe ìwé àkọsílẹ̀ láti ma kọ orúkọ àwon olukọ to ba hùwà ibajẹ naa.