Rashidi Ladọja: Igbákejì gómìnà Ọyọ ní Ladọja ṣe bẹbẹ lẹ́ka ètò ẹkọ́

Tẹbi tara ati awọn aṣoju ijọba lo peju-pesẹ lati ṣe ajọyọ ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun karundinlọgọrin gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Oloye Rashidi Adewọlu Ladọja.

Ayẹyẹ naa ti o waye ni gbọngan nla igbalejo ile itura 'Premier Hotel' ilu Ibadan l'ọjọ Aje, jẹ ọkan lara akanṣe eto to waye nibi ifilọlẹ iwe eto ẹkọọ nipa itan ati ipo adari ti aya gomina tẹlẹri naa, Arabinrin Bukọla Ladọja kọ fun awọn ile ẹkọọ to n bẹ lorilẹede yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ Onimọẹrọ Rauf Ọlaniyan, ti o ṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ nibi ipejọpọ naa, gbosuba kare fun Oloye Rashidi Ladọja fun iṣẹ takuntakun ti o ṣe fun idagbasoke ipinlẹ Ọyọ, lasiko iṣejọba rẹ gẹgẹ bii gomina, paapaa julọ lẹka eto ẹkọ.

Ọlaniyan tẹsiwaju wi pe, ibi ti ọrọ eto ẹkọ ti wọ ni ẹkun iwọ-oorun ni Ladọja mojuto lasiko iṣejọba rẹ, ki o to di wi pe awọn ti o gba ijọba lọwọ rẹ da eto naa ru.

O fi kun ọrọ rẹ wi pe, ijọba ipinlẹ Ọyọ n tọrọ ẹmi gigun ati alafia fun baba ọlọjọ ibi, ti Kọmisana fun eto ẹkọọ ati imọ ijinlẹ nipinlẹ Ọyọ, Ọjọgbọn Kehinde Sangodoyin naa si farahan nibi ayẹyẹ ọhun.

Ninu ọrọ rẹ, Sangodoyin ṣe apejuwe Oloye Ladọja gẹgẹ bii baba gidi, o ni lati igba ti gomina tẹlẹri naa ti n dije du ipo ni oun ti ṣe alabapade rẹ.

O tẹsiwaju wi pe Ladọja jẹ ẹni ti o maa n fẹ ki nnkan rere ti akata rẹ jade wa, bẹẹ si ni o maa n fẹ ki gbogbo eeyan ṣe daadaa, bakan naa lo ni o jẹ ẹni kan ti kii bẹru, eyii si jẹ nnkan pataki to yẹ ki gbogbo eeyan ṣe awokọṣe rẹ.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ikọ iroyin BBC Yoruba, arabinrin Bukọla Ladọja ṣe alaye wi pe ipa ribiribi ti Oloye Ladọja ko fun idagbasoke eto ẹkọọ lasiko iṣejọba rẹ, lo mu ki wọn ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi naa mọ ifilọlẹ iwe tuntun ti aya gomina tẹlẹri naa kọ.

Arabinrin Bukọla wa parọwa si Oloye Ladọja lati tẹsiwaju ninu iṣẹ rere, paapaa julọ lẹka eto ẹkọọ.

Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Oloye Rashidi Ladọja dupẹ lọwọ gbogbo awọn arirebaniṣe pẹlu adura pe ohun rere ko ni tan lọdẹdẹ ẹnkẹni.

Ladọja ṣe alaye wi pe, lara awọn iredi ti idagbasoke eto ẹkọ fi jẹ oun logun ni wi pe oun gan ti jẹ anfani eto ẹkọọ ọfẹ sẹyin, bẹẹ si ni oun mọ ohun ti o tumọ si fun akẹkọọ lati joko sile nitori aisan owo ile ẹkọọ.

Gomina tẹlẹri naa fi kun ọrọ rẹ pe, lara ohun ti o yẹ ki ijọba to n bẹ lode tẹsiwaju lati maa ṣe, ni itọju awọn olukọ nipasẹ sisan owo oṣu wọn lasiko.

Ladoja ni oun ko ni dẹkun lati maa kopa ninu idagbasoke eto ẹkọ lawujọ, bo ti wu ki ara di ara agba to.

Ọkanjọkan orin ni wọn fi da awọn alejo lara ya nibi ayẹyẹ naa.

Lara awọn eeyan ti o tun wa nikalẹ ni Ọjọgbọn Bọlanle Awe, adari awọn oṣiṣẹ gomina ipinlẹ Ọyọ, Oloye Bisi Ilaka, akọwe ijọba ipinlẹ Ọyọ, Arabinrin Olubamiwo Adeoṣun, awọn lẹgbẹlẹgbẹ loyeloye ati bẹẹbẹẹ lọ.