Lagos State: Ẹbí èèyàn márùn ún àti àlejò kú sínú ilé l'Eko

Igbe oro lawọn agbebe lawọn olugbe agbegbe Mafoluku l'Oshodi n ke l'Ọjọru lẹyin ti wọn ba oku eeyan meje pẹlu alejo wọn ninu ile laarọ Ọjọru.

Nọmba 19, Olowora ni awọn ara adugbo Mafoluku ti ri oku ọkunrin kan, ati iyawo rẹ pẹlu awọn ọmọ mẹrin ati alejo wọn ti oyun wa ninu rẹ.

Iroyin ti a gbọ ni pe iṣẹlẹ ọhun waye ninu yara kan tawọn eeyan naa sun si.

Ko si ẹni to mọ pato ohun to ṣe okunfa iku wọn ṣugbọn awọn kan ni o ṣeeṣe ki wọn jẹ majele mọ ọunjẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ko gbe ago nigba ti BBc Yoruba pe wọn lati mọ ohun to ṣokunfa iku awọn eeyan naa.