World Economic Forum: A ò kópa mọ nínú àpérò ètò ọrọ ajé ní Cape town- Ìjọba Nàìjíríà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ìjọba Nàìjíríà tí kédé pé òun ti yọwọ́ kúrò nínú ìpàdé àpérò ètò ọ̀rọ̀ ajé àgbáyé tí yòó wáye ni Cape Town lórí ọ̀rọ̀ àkọlù tí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè South Africa ń ṣe si àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fẹnukò lórí ọ̀rọ̀ yìí lásìkò ìpàdé láàrin Ààrẹ Muhammadu Buhari, ìgbákeji rẹ̀ Yemi Osinbajo àti mínísita fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè Geoffrey Onyeama tó wáyé ilé ìjọba ní ìlú Abuja.

Bakan náà ní ìjọba ti ń ròó pé ki asoju ijọba ni orílẹ̀-èdè South Africa Kabir Bala ó pada sílé, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn NAN ṣe sọ

Ààrẹ Buhari ń gbe yẹ̀wò boyá yóò bọ̀wọ̀ fún ìpè ààrẹ South Africa ààrẹ Cyril Ramaphosa lọ́ri àkọlu tó n wáye.

Tí ẹ o bá gbàgbé Ramaphosa tí pé ààrẹ Buhari láti wá si orilẹ̀-èdè South Africa ní ọjọ kẹta oṣu kẹ̀wáà láti fọ̀rọ̀wẹ́rọ̀ lójùnà àti mú ìṣọkàn wà láàrin orílẹ̀-èdè méjèèjì