Ogun Kidnap: Ìjàmbá ṣàwọn ajínigbé tó fẹ́ fipá gba akẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́ ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ogun Police Command
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kepe awọn eeyan ati ile iwosan kaakiri ipinlẹ naa pe ki wọn kan si ile iṣẹ ọlọpaa ti wọn ba ri ẹnikẹni to ba ni apa ibọn lara.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi to ba BBC Yoruba sọrọ, ṣalaye pe awọn akẹgbẹ awọn ajinigbe mẹrin ti ọwọ awọn ọlọpaa tẹ lo doju ija kọ awọn ọlọpaa nigba ti wọn n kọ wọn si Abeokuta lati Ode Omi ti wọn ti ji ọmọ Imaamu ati eeyan meji mii gbe.
DSP Oyeyemi fidi rẹ mu lẹ pe ibọn ọkan lara awọn to doju ika kọ awọn ọlọpaa naa gbẹmi mi tawọn yoku si farapa.
- Ta ni Ọjọgbọn Adebanji Akintoye tó borí Tinubu láti di olórí àwọn Yoruba?
- Afẹ́nifẹ́re kìí ṣe asọju ọmọ Yorùba ẹgbẹ́ lásàn ní wọ́n
- Èmi àti Saheed kìí ṣe ọmọdé, a ti jọ ṣe Sinimá papọ̀, èyí túmọ̀ sí pé ìjà ti parí - Fathia Balogun
- Ọ̀pọ̀ èèyàn bẹnu ẹ̀tẹ́ lu Mercy Aigbe lórí bó ṣe ki Adeniyi Johnson
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Nitootọ ni ìdìbò míràn á wáyé ní Kogi, mo máa di gómínà ni -Dino
Ọgbẹni Oyeyemi ni iwadii si n lọ lọwọ lori awọn ajinigbe to fara gbọta nitori ko sẹni to tii sọ ohun kan fun ileeṣẹ ọlọpaa di akoko yii.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti kọkọ doola awọn mẹta ti wọn jigbe lọsẹ to lọ.
Ẹwẹ, DSP Oyeyemi tun ṣalaye pe ileeṣẹ ọlọpa si n wa ọkọ oju omi agbera pa wọn tawọn ajinigbe gbe lọ nigba ti wọn fi doola ọmọ Imaamu atawọn meji ti wọn gbe lọwọ wọn.
O ṣalaye pe awọn ọlọpaa fẹ kọkọ wa awọn ajinigbe ri ki wọn to wa ọkọ oju omi.








