You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sanwó Olú búra fún ìgbìmọ̀ ìṣàkóso rè níbi tó ti yan àwọn 38 sípò
Ni ọjọ Isegun ọ̀sẹ̀ yìí ni gomina ìpínlè Èkó, Ogbeni Babajide Sanwó Olú ṣe ifilole igbimo ìjọba rẹ ni ọ́fíìsì ijoba ni Alausa Ikeja.
Eniyan mẹta lára awọn méjìdínlogoji tí wón fi orúkọ wọn ṣọwọ sílè Ìgbìmò asofin ipinlẹ Eko ni wọn yọ kuro Sanwo Olu yan kọ̀míṣọ́nnà 25 àtàwọn olùbádámọ́ràn.
Àwọn metẹẹta ni: Àjàyí Bembe tó wá láti aarin gbùngbùn Ikoyi; Olanrewaju Sanusi láti ẹkùn Ikorodu àti Obafemi George láti ijoba ibile Eti Ọsa.Gomina Babajide Sanwó Olú, kò sai yàn àwọn ènìyàn láti ẹ̀yà mìíràn láti Gúúsù ìlà Òòrùn ilé yìí àti Ariwa Orílẹ̀ èdè yìí bakan naa.
Ẹni tí ó wà láti Gúúsù ìlà oòrùn ni Ogbeni Sam Egube.
Nigbà ti Arabinrin Uzamat Yusuf Akinbile wa lati apa ariwa Naijiria.
Iroyin ni awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko lo yọ orukọ wọn lẹyin ti Sanwo Olu fi ranṣẹ sile.
Opolopo awuyewuye ni ikede yii ti n bi lori ayelujara ti awọn eniyan si n fi ero ọtọọtọ han nipa iṣẹlẹ yii..Awọn kan sọ pe Sanwo Olu paapaa ko tii pade awọn miran ninu awọn kọmiṣọna naa ri rara
Awọn miran gba pe agbara to ju agabra lọ lo yan awọn eeyan yii fun gomina.
Sanwo Olu funra rẹ gba pé awọn ti oun yan yoo ran oun lọwọ lati wakọ ipinlẹ Eko de ebute ogo laipẹ
Awọn eniyan ipinle Eko kan parọwa fun gomina Sanwo Olu pe eebu alọ ni tahun ni ọrọ naa yoo di ti awọn to yan sipo ko ba ṣiṣẹ bi o ti yẹ.
Bẹẹ lawọn miran gboriyin fun gomina Sanwo Olu pe awọn agbagbọ ninu rẹ pe yoo yan awọn to yẹ sipo.
Ọpọ ni ki wọn ṣetan lati tun igbe aye awọn eniayn ipìnlẹ Eko ṣe lasiko yii ti a ti yan wọn sipo lai huwa awa ko mọ pe ebi n pa ọmọ ẹnikọọkan.