Kidnappings in Nigeria: Ajínigbé ń bèèrè fún epo, iṣu àti ọ̀tí Schinap àti owó ìtanràn

Awọn ajinigbe ni apa iwọ oorun guusu Naijiria tun gba ọna ara ọtọ jade si ẹbi ẹni ti wọn ji gbe.

Gẹgẹ bi iroyin ti ile iṣẹ iroyin NAN ti Naijiria fi sita lẹyin iwadii pe ibeere wọn tun yatọ lọtẹ yii.

Agba kan ninu mọlẹbi awọn mẹta ti wọn ji gbe naa ṣalaye pe kete ti awọn ajinigbe ti kan si mọlẹbi ni wọn ti kede nkan ti wọn fẹ gba.

O ni lẹyin-o-rẹyin ni awọn mọlẹbi san agba epo pupa jálá lita ọgbọn, ọti Schinapu, ọpọlọpọ iṣu ati miliọnu mẹta ati aabọ naira.

Awọn mọlẹbi ṣalaye pe ọdun Ileya to kọja ku ọla ni awọn ajinigbe yii gbe awọn mẹtẹẹta.

Agbegbe Odẹ-Omi to paala laarin ẹya kan si ikeji laarin ipinlẹ Eko ati Ogun ni wọn ti ji wọn gbe.

Kọmiṣọna ọlọpaa, Bashir Makam ni wọn ko san owo itanran kanakna lati fi doola ẹmi awọn eniyan yii ṣugbọn mọlẹbi wọn ni pe irọ ni.

Mọlẹbi yii to ni ki wọn fi orukọ bo oun laṣiri ni" A gbe owo itanran miliọnu mẹta ati aabọ pẹlu paali Schinaapu kan ati jálá lita epo pupa ọgbọn ati iṣu nlanla mẹwaa ati ororo jala lita marun un lọ fun wọn.

O ni lẹyin eyi ni wọn to ri awọn mẹtẹẹta gba pada lẹyin ọdun Ileya.

Abimbọla oyeyẹmi to jẹ agbẹnusọ ajọ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun ni awọn agbofinro ko mọ nipa owo itanran ati ohun jijẹ yii rara.

O ni: "awa ọlọpaa ẹkun yii lo ṣokunfa bi wọn ṣe ri awọn eniyan yii gbe ṣugbọn a ko mọ nipa owo itanran rara".

Opọ ẹmi lo ti sọnu ti awọn eniyan si ti san owo to pọ gẹgẹ bi owo itanran kaakiri Naijiria lasiko yii.