Àwọn olóṣèlú ló fẹ́ sọ darandaran Fulani lórúkọ burúkú, àwa kìí gbébọn-Miyetti allah

Ẹgbẹ agbajọpọ awọn darandaran Fulani lorilẹede Naijiria, Miyetti Allah, ti wa jade lati pariwo ẹ ma sọ wa ni suna buruku, ko si ọmọ ẹgbẹ wa to n gbe ibsn fi daran igi ni wọn nlo.

Aarẹ ẹgbẹ Miyetti Allah, Bello Abdullahi Bodejo lo sọ bẹẹ lasiko to fi n yannana ọrọ ni ilu Bauchi.

O ni bi awọn eeyan ṣe n sọ Fulani ni suna ti kii ṣe ti wọn nipa pipe wọn ni darandaran to mu iṣẹ ọdaran mọ iṣẹ ko bojumu to.

O ni ki ẹ si maa wa wo o, awọn o jẹ nile oro jẹ nile eegun oloṣelu ni wọn wa nidi ọrọ yii ati pe awọn ọta ẹya Fulani naa wa nidi ẹ; ṣe ẹ si mọ pe eeyan kii wa laye ki o ma ni ọta tirẹ naa.

Bello Abdullahi Bodejo tun ko aroye balẹ o ni, gbogbo ọran ijinigbe pawo tabi pa, idigun jale atawsn iwa ọdaran miran ti wọn n so akengbe ọran rẹ mọ awọn Fulani lọrun lori oju opo ayelujara gbogbo lawọn kan gbe kalẹ o lati ba orukọ awọn ọmọ ẹya Fulani jẹ.

O ni wahala laarin awọn agbẹ olohun ọgbin atawọn darandaran to jẹ Fulani ti pẹ bi ọwọ aṣọ, awsn eeyan kan lo kan fẹ bẹrẹ si ni fi oṣelu pọn jẹbẹtẹ lakisa lori rẹ

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, awọn igun mejeeji yii lo mọ bi wọn ṣe n pari aawọ ati dukuu aarin wọn.