You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Asset Declaration: Gbogbo ẹni tí ó máa búra wọlẹ́ gẹ́gẹ̀ bíi Mínísítà gbudọ̀ kéde dùkìá
Igbimọ eleto idajọ to n gbọ ẹsun iwa aṣemaṣe awọn eeyan to dipo oselu mu ati oṣiṣẹ ọba, CCB ti paṣẹ fun awọn ti aarẹ Buhari fẹ yan sipo minisita lati kede dukia wọn ki wọn to ṣebura wọle tabi ki w n koju ofin.
Ajọ naa n gbero lati ṣewadi awọn dukia naa ni ẹka ijọba to n ṣabojuto ọrọ ilẹ, ile ifowopamọ ati awọn ile iṣẹ ti wọn ba ni, ati eyi ti wọn ba nipin ninu rẹ.
Siwaju si, ajọ naa yoo tun ṣiṣẹ pẹlu ile iṣẹ otẹlẹmuyẹ lati wadi awọn dukia ti wọn ba ni ni oke okun.
Alaga CCB, Prof. Muhammed Isah wi pe ko si ẹnikẹni ninu awọn minisita tuntun naa ti wọn yoo ṣebura wọle fun lai kọkọ kede dukia wọn.
O tun ni lara awọn minisita yii ti gba iwe ikede dukia bẹẹni awọn miran ko tii gba.