Community Policing: ìjọba ìbílẹ kọọkan yóò gbà ààdọta òsìsẹ

Oríṣun àwòrán, Policeng
Gbogbo ijoba ibile merinleniaadorino le ni eedegbeje ni eto naa yoo ti waye.
Ìlé iṣẹ ti kẹde láti gba àwọn òṣiṣẹ ẹgbẹrún lónà ogójì tí yóò maa ṣe ọlọpàá àdúgbò tí àwọn ọmọ Nàìjíríà tí ń pè fún kí ọrọ ètò ààbò òrílẹ-èdè yìí tó dé ibi ti ó de dúró yìí.
Ìlé iṣẹ ọlọpàá ní àwọn yóò gba òsìṣẹ kọọkan láti àgbègbè tí wọn bá n gbé, ó kéré tán ẹnìyàn ààdọtá láti ìjọba ìbìlẹ kọọkàn jákejádò orílẹ-èdè Nàìjíríà
- Jesu orí ayélujára kan rèé tó wa fun isoji ni Afirika
- Arẹ́májà kò sí, Olubadan fi tìlù-tìfọn kí àwọn ìjòyè káàbọ̀ lẹ́yìn ọdún méjì
- Àṣírí mẹ́wàá tí mo mọ̀ nípa Boko Haram-Naomi Adamu
- Ọkùnrin méjì, obìnrin mẹ́ta jáde láyé ní Mecca lásìkò Hajj 2019 - NAHCON
- Èèkànlú ní ìpínlẹ̀ Ogun lọ kí Buhari l‘Abuja torí ẹ̀yẹ tó fi dá Abiọla lọ́lá
Bákan náà ni wọn fí kún un pé ènìyàn ọọdúnrún lé ni ẹgbẹrún ní àwọn ní yóò gbà sísẹ nínu àwọn akọṣẹmọṣẹ àti àwọn ẹgbẹ ọdọ ní Nàìjíríà.
Lórí òpò twitter ilé iṣẹ olopaa ní ìròyín náà ti jáde.
Bakan náà ni ọgá àgbà ọlọpàá Muhammed Adamu kédé rẹ nínú ìpàdé kan to pé fún àwọn ọgá ọlọpàá nílu Abuja níbi tó ti sàlàyé kíkún lóri fífòfin dé àwọn ọmọ egbẹ Shi'ite tó ń tèlé El-ZakyZakky, olori Islamic Movement in Nigeria (IMN).
O menuba igbese ijoba ti yoo jade laipe.













