Ààrẹ Beji Caid Essebsi, torílẹ̀èdè Tunisia jáde fáyé

Oríṣun àwòrán, AFP
Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́lọ́wọ́ ní wí pé Aarẹ akọkọ ti wọn kọkọ finu findọ yan ni orilẹede Tunisia, Beji Caid Essebsi ti jade laye lẹni ọdun mejilelaadọrun.
Ileeṣẹ aarẹ orilẹede Tunisia lo kede rẹ.
Oun ni aarẹ to dagba julọ lagbaye.
- Google bẹ̀rẹ̀ sí lo ohùn Nàìjíríà lórí ẹ̀rọ̀ ajúwe ọ̀nà
- Agbébọ́n tún ṣoro ní márosẹ̀ Ibadan sí Eko, wọ́n jí èèyàn mẹ́ta gbé
- Ta ló ni $1.6m táwọn ọmọ ogun jí gbé sálọ nínú ọkọ̀ agbówórìn?
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àwọn obìnrin méje ti Buhari forúkọ wọn ránṣẹ
- Kò sí ìwé ìrìnnà 'VISA' fáwọn ọmọ Naijiria tó hùwà àìtọ́ nígbà ìdìbò
Wọn gbee lọ sileewosan ni ọjọru bi o tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ ilẹ naa ko sọ idi to fi lọ gba itọju nileewosan.
Ni ọdun 2014 ni ọgbẹni Essebsi bori ninu idibo apapọ ti awọn orilẹede naa ṣe lọdun 2014 lẹyin wahala awọn larubawa lagbegbe naa.
Ṣaaju ni ọdun yii, o kede pe oun ko ni dije fun ibo mọ lasiko idibo orilẹede naa ti wọn n fojusọna nigba naa pe yoo waye loṣu kọkanla ọdun yii.
Iroyin sọ pe wọn gbe aarẹ Essbsi lọ sileewosan ni oṣu to kọja nitori ohun ti awọn alaṣẹ orilẹede naa kan pe ni 'wahala ilera to lagbara gidigidi'
Nigba naa, olotu ijọba orilẹede ọhun, Youssef Chahed to bẹẹ wo nileewosan rọ awọn eeyan lati yẹra fun iroyin irọ nipa ipo ilera rẹ nigba naa.
Wọn yọ Aarẹ Tunisia nigba kan ri, Zine el-Abedine Ben Ali ni ọdun 2011 lẹyin to lo ọdun mẹtalelogun ni ipo.
Lati igba yii wa ni orilẹede Tunisia ti gba oriyin gẹgẹ bi orilẹede kan ṣoṣo lagbaye to gba eto iṣejọba tiwantiwa labẹ abajade iwọde ẹhonu araalu eyi ti wọn pe ni arab spring.
A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.
Awọn Iroyin mii ti ẹ le nifẹ sii
- Barrister ló sọ mí di èèyàn ńlá - Ayinla Kollington
- Ìtàn tó wà nídi òwe ‘Sebótimọ Ẹlẹ́wà Sàpọ́n’
- Ìtàn tó rọ̀ mọ́ òwe ‘aṣọ kò bá Ọ́mọ́yẹ mọ́...’ rèé
- Afọnja, ẹni tó finú wénú ní Ilọrin, àmọ́ tó jẹ iwọ
- Ẹfunsetan Aniwura, obìnrin tó ju ọkùnrin lọ
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, Aláàfin obìnrin àkọ́kọ́ rèé, tó ní nǹkan ọkùnrin














