Thomas Crowther ṣe àtúpalẹ̀ ìwádìí yìí ni orilẹ-ede àádọrin ní àgbáyé
Igi n fún kòkòrò ní ṣúgà -Thomas Crowther
Iwadii yii ni akọkọ iru rẹ lagbaye to maa ṣe atupalẹ aṣiri igbe aye awọn igi ninu igbo.
Bufunmi ki n bu fun ọ ni ajọṣepọ to wa laarin igi igbo ati awọn kokoro inu igbo gẹgẹ bi iwadii ti onimọ ijinlẹ Thomas Crowther fidiẹ mulẹ.
Awọn kokoro maa n pese eroja aṣaraloore fun igi ninu igbo bi ohun naa ṣe n pese ṣuga.
Onimọ nipa ibaṣepọ laarin irugbin ṣe iṣe iwadii yii ni aadọrin orilẹ-ede kaakiri agbaye ni.
Iwadii ti Thomas Crowther atawọn ẹgbẹ rẹ ṣe yii lo jẹ ki a mọ pe o le ni ida ọgọta igi ti wọn jọ n ni ibaṣepọ pẹlu ara wọn ninu igbo.