You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Seyi Makinde gbàlejò Abdulsalami Abubakar ní Ibadan
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti se apejuwe adari orilẹede Naijiria nigba kan ri, Abdusalami Abubakar gẹgẹ bi baba to ni ifẹ si ilosiwaju orilẹẹde Naijiria.
Seyi Makinde sọ eyi lasiko to n gbalejọ Abubakar Abdusalami ni ilu Ibadan.
Makinde ni ijọba ti setan lati se ohun gbogbo to yẹ lati ri wi pe eto aabo gbooro si ni ipinlẹ Ọyọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Abdusalam, nigba to n fesi, gboriyin fun gomina Makinde, to si ni ọgbọn ati imọ to n lo nigba to n sisẹ aladani yoo ran an lọwọ lati tukọ ipinlẹ naa de ibi aseye.
Adari Naijiria nigba kan naa wa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ lati ri wi pe wọn seto igbaye gbadun fun awọn olugbe ipinlẹ naa.
Ọgaagun Abdulsalami Abubakar jẹ adari orilẹede Naijiria ni ọdun 1998 si ọdun 1999.
Seyi Makinde ati Adari Ile Asofin Ipinlẹ Ọyọ, Adebo Ogundoyin lo fi tọwọtọwọ ki Abdusalami Abubakar kaabọ si ipinlẹ naa.
Gomina naa si fi ami ẹyẹ aworan ti wọn fi owo ya, da ajagunfẹyinti naa lọla.
- Poly Ibadan: Ọjọ́ iwájú la rò táa fí dáná sún fóònù àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Ìwọ báwo! Bí Nàíjíríà ṣe jáwée jókòo jẹ́ fún South Afrika rèé
- Sanwoolu ṣe é dáa fún wa níbodè Lekki, Ikoyi - Awakọ̀ ní Lekki
- Kí ni Bode 'Thomas' ní ṣe pẹ̀lú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Nàìjíríà àti South Africa?
- Ọ̀nà tó fi le è mọ gbájúẹ̀ babaláwo - Ẹlẹ́buìbọn