You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Collapsed Building: Ẹ̀mí kankan kò bọ́ nínú ilé míràn tó wó ládugbó Kakawa l'Eko
Iṣẹlẹ ile wiwo nilu Eko ti wa fẹ di ohun to peleke lẹnu ọjọ mẹta yi pẹlu bi ile miran ṣe tun dawo nisale Eko.
Adugbo Kakawa ni a tun gbọ pe ile miran ti dawo lọjọ Aje.
Gẹgẹ bi iroyin ti o tẹwa lọwọ ti wi, ko si ẹmi kankan to padanu ninu iṣẹlẹ tuntun yi.
Iṣẹlẹ ile wiwo yii ni yoo jẹ ẹlẹkẹtaa ti yoo waye nilu Eko laarin ọsu kan.
Ko ti daju ohun ti o fa iṣẹlẹ ile wiwo tuntun yii ṣugbọn asoju fun Lagos Island nile asofin ipinlẹ Eko, ọgbẹni Sola Giwa,fidi ọrọ naa mulẹ.
Ninu ohun ti o sọ, o ni ko si ẹmi kankan to padanu ninu iṣẹlẹ naa ati wi pe ijọba ti ṣami si ile naa gẹgẹ bi ọkan lara awọn ile ti wọn fẹ wo.
Lọjọ kẹtala Osu yi ni ile alajamẹrin kan dawo ladugbo Ita Faji nibi ti eeyanogun ti padanu ẹmi wọn.
Ko pẹ si igba naa, ni ile miran tun dawo ni adugbo Egerton Square, Oke Arin ni Isale Eko kannna.
Ijọba ipinlẹ Eko lẹyin iṣẹlẹ Ita Faji ti bẹrẹ si ni wo awọn ile ti ko duro daada lati dena ijamba ẹmi ati dukia.