You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
2019 Election update: Buhari àti Ọṣinbajo gba ìwé ẹ̀rí Mo yege
Aarẹ Muhammadu Buhari, to sẹsẹ jawe olubori fun saa keji ti lọ gba iwe ẹri 'Mo yege' lọdọ ajọ eleto idibo nilu Abuja.
Aarẹ Buhari ati igbakeji rẹ, Yẹmi Ọsinbajo ni wọn dijọ lọ gba iwe ẹri naa.
Nigba to n fun wọn ni iwe ẹri naa ni gbọngan nla ICC to wa nilu Abuja, Igbakeji aarẹ ati iyawo rẹ ni wọn kọks lọ gba iwe ẹri naa, ko to kan aarẹ funra rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjọba paṣan ní Nàìjíríà dibo fún, yóò kàn gbogbo wà-Sowore
- Atiku: Màá foríji àwọn tó kówó ìlú jẹ́ tí mo bá di àárẹ
- A kò ní fárí apá kan, dá apá kàn sí nínú ìjọba wà - Buhari
- Ẹ wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká sẹ́nẹ́tọ̀ tó kùnà nínú ìdìbò ilé aṣòfin
- Buhari la Atiku mọ́lẹ̀, o di ààrẹ Nàìjíríà tuntun
- Ìdí tí mo fí kọ̀ èsì ìbò ààrẹ - Atiku ṣàlàyé
- Ìjọba paṣan ní Nàìjíríà dibo fún, yóò kàn gbogbo wà - Sowore
Ninu ọrọ rẹ nibi ayẹyẹ gbigba iwe ẹri Mo yege ọhun, eyi ti ọpọ eeyan peju si, aarẹ Muhammadu Buhari ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe eto idibo naa tọri si rere.
O ni o daju pe eto idibo naa lọ lai si kọnu n kọhọ ninu, taa ba wo iwoye awọn eeyan to wa tọpinpin ibo naa lati ilẹ okeere.
Buhari wa kesi awọn alatilẹyin rẹ lati mase yọ awọn igun alatako, amọ ki gbogbo wọn dijọ gbaruku ti oun lati mu ki Naijiria tẹsiwaju.
O ni oun yoo gbe isejọba ti yoo lọwọ gbogbo eeyan ninu, ti yoo si ba ala gbogbo wa mu fun orilẹede Naijiria to dara, ti aabo to peye wa nibẹ.
Buhari ni oun ko ni afojusun miran bikose lati sin Naijiria tọkantọkan, eyi ti yoo duro re, tinu awọn ọiran to n bọ yoo si fi yangan,
Aarẹ orilẹede yii tun fi ọwọ idaniloju sọya pe oun yoo ms le ọpọ aseyọri oun nipa tita ọrs aje orilẹede yii ji, pipese eto aabo to duro re ati gbigbogun ti iwa ajẹbanu.
Bakan naa ni Buhari daro pẹlu awọn eeyan ti ẹmi wọn bọ lasiko eto idibo yii, boya nitori laasigbo to waye ni abi lati ipasẹ ijamba ọkọ, to si gbadura pe ki Ọlọrun tk wsn si afẹfẹ rere.
Aarẹ Buhari woye pe eto idibo kii se ogun tabi ọtẹ, bẹẹ ni kii se boo ba o pa, boo ba, ko bu lẹsẹ.
A kò ní fárí apá kan, dá apá kàn sí nínú ìjọba wà - Buhari
Aarẹ orileede Naijiria to wọle fun saa keji, Muhammadu Buhari ti dupẹ lọwọ awọn eeyan orileede wa fun aseyọri rẹ ninu idibo aarẹ to waye.
Lowurọ Ọjọru ni ajọ eleto idibo Inec kede rẹ gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo aarẹ to waye lọjọ abamẹta.
Ko pẹ pupọ lẹyin ikede yii ti Buhari ati awọn ọmọ ẹgbẹ APC ti peju si olu ileeṣẹ ẹgbẹ naa ni Abuja nibi ti o ti fi ọrọ ikini ranṣẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ni iwaju awọn ọmọ ẹgbẹ APC lolu ile ẹgbẹ naa, Buhari ni ayọ ohun kun nitori ifẹ ti awọn eeyan fi han si ohun lati jẹ aarẹ lẹẹkansi.
O ni inu oun bajẹ pe awọn eeyan padanu ẹmi wọn ninu idibo naa, to si rọ awọn osisẹ eleto aabo lati tẹramọ iṣẹ wọn lasiko idibo Gomina to n bọ lọna.
Lara awọn ti wọn jijọ peju si ile ẹgbẹ naa ni awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC ati awọn alatilẹyin ẹgbẹ naa.
Aarẹ Buhari wa rọ awọn alatilẹyin rẹ lati mase fi awọn alatako ṣe yẹyẹ .
Buhari ni ijọba ohun yoo tẹramọ mimu agbega ba eto aabo,ọrọ aje ati kikoju iwa ajẹbanu.