Nigeria Elections 2019: Ìjàmbá iná àti àwọn nkan mi i tó mú INEC sún ìdìbò

Alaga ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, Yakubu Mahmood ti sọ wi pe kii ṣe aṣẹ ẹnikẹni lo mu ki ajọ naa sun eto idibo aarẹ ati ti ile aṣofin apapọ to yẹ ko waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keji siwaju.

Yakubu, lasiko to n ba awọn eniyan sọrọ ni gbọngan ti wọn ti maa n ko esi isibo jọ to wa ni ilu Abuja sọ pe ''ijamba ina, oju ọjọ ti ko dara to lati fi baalu gbe eroja idibo, ati idiwọ ninu eto gbigbe awọn eroja idibo lo mu ka sun eto idibo naa siwaju.

'Ko ni nkankan ṣe pẹlu eto aabo tabi aṣẹ lati ọdọ ẹnikẹni.''

O tọka si ijamba ina to waye ni awọn ileeṣẹ ajọ naa to wa ni ipinlẹ Anambra, Abia ati Plateau.

Mahmood sọ pe 'oun tọrọ aforiji fun sisun eto idibo naa siwaju, ati pe oun gba gbogbo ẹbi naa mọra.

Bakan naa ni Ọjọgbọn Yakubu kede pe ko si aaye fun ẹgbẹ oṣelu kankan lati polongo ibo nitori sisun ti wọn sun eto idibo siwaju.

Ati pe ko ẹnikẹni ko ni le ri kaadi idibo gba titi di ẹyin idibo.

Ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtadinlogun, osu Keji ọdun 2019 ni idibo aarẹ yoo waye.