Nigeria Elections 2019: Àwọn ọmọ Nàìjíríà n ṣé hèèmọ̀ bí INEC ṣé dajọ sí ibo

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Kini ka ti ṣe eyi si?

Ọrọ ti o gba ẹnu ọpọ ọmọ Naijiria ree lẹyin ti ajọ eleto idibo orile-ede Naijiria da ọjọ si idibo Aarẹ ati ti awọn aṣoju ile aṣofin ti o yẹ ki o waye lọjọ Abamẹta.

Ọrọ naa ṣe ọpọ ni kayefi lataari pe ajọ naa ko tawọn lolobo pe irufẹ iṣẹlẹ bayi yoo waye.

Loju opo Twitter iyalẹnu ni o kọkọ bẹrẹ iriwisi awọn ọmọ Naijiria nigba ti iroyin naa wọ wọn lara tan, ṣeni ọpọ bẹnu ẹ̀tẹ́ lu INEC

Ikanra lawọn miran fi n fẹsi si ikede yi.

Ogbeni Dipo yatọ si pe o gba adura fun itusilẹ Naijira faraya pe awọn ọmọ orile-ede kan rin irinajo wakati marun un lati le lọ dibo eleyi ti ko waye mọ

Iha miran lọrọ yi kọ si ẹlomiran bi Naturalguy4eva ti o n kaanu awọn ti wọn ti dajọ igbeyawo si ọjọ kẹtalelogun Osu keji ti Inec sun idibo naa si