#NigeriaDecides2019: ‘Kò sí àríyá lónìí, kò tún sí ìbò dídì, irú Sátidé mímọ́ wo rèé’

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Kii se iroyin mọ pe ajọ eleto idibo nilẹ wa, INEC, ti wọgile eto idibo aarẹ to yẹ ko waye lọjọ Satide oni.

Ni kete tawọn ọmọ Naijiria si ti gbọ iroyin agbọgbọntinu ọhun ni wọn ti n sọ oniruuru ero wọn nipa ikede yiii.

Lori awọn opo ikansiraẹni lori ayelujara bii Facebook, Twitter, Instagram ati Whats App, ẹnu ko gba iroyin nipa ohun tawọn eeyan n wi lori isẹlẹ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn ohun ti wọn kọ to pa ni lẹrin ni bi awọn eeyan kan se ni orilẹede Naijiria su awọn, ti wọn si n wa ọna lati tẹ ọkọ leti lọ soke okun.

Lawọn oju opo Facebook, igbe to gba ibẹ kan ni pe ‘Ko si ayẹyẹ igbeyawo ta fẹ lọ loni ọjọ, ko si ayẹyẹ oku sise, ko si ibi kankan ta fẹ lọ, wọn tun wa ni a ko lee dibo mọ. Iru Satide mimọ wo ni eyi lorilẹede Naijiria.’

@raph_shalom, ọpọ ibeere lo n beere lati sa kuro ni Naijiria.

@d_boy_nextdoor, o ni orilẹede Naijiria nikan lati lee gbọ iru iroyin YajoYajo bayii, to si fi aworan kan to pa ni lẹrin sidi rẹ.

Ademola Aremu lori Facebook ni ‘o seni laanu pe awọn wolii ariran wa ko ri saaju pe ajọ eleto idibo yoo sun ibo siwaju ni Naijiria sugbọn awọn ti yoo bori ibo ni wọn n ri.’

Bakan naa ni awọn eeyan orilẹede Ghana tun n fi wa se yẹyẹ ni Naijiria lori ba se sun ibo aarẹ siwaju lọjọ idibo gangan.

IssahakuB.Gbene lori Facebook ni ‘Awọn ọmọ Naija yii saa, Wọn ko lee se raisi Jọllọfu, bẹẹ ni wọn ko tun lee seto idibo lasan. Yatọ si ẹba ati ọbẹ ewuro tẹ mọ se, ki lẹ tun lee se gan?