Ọbanikoro: Àjọṣepọ̀ tó wà láàárín èmi àti Fayose kò ní jẹ́ ki ń tú àṣírí

Igbẹjọ gomina ana ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe lori ẹsun ṣiṣe owo to le ni biliọnu meje naira (N7.2b) baṣubaṣu ti ajọ EFCC fi kan an, waye lọjọ Aje ni ile ẹjọ giga apapọ to wa ni Eko.

Minisista abẹle feto aabo nigbakanri, Musiliu Obanikoro lo n jẹjọ tako Fayoṣe niwaju ile ẹjọ, lori bo ṣe ni oun fun Fayoṣe ni miliọnu marun un dọla owo ilẹ Amẹrika lara owo iyasọtọ fun ofiisi alamojuto eto aabo lorilẹ-ede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agbẹjọro fun Fayoṣe fi ọrọ wa Ọbanikoro lẹnu wo fun nnkan bii wakati meji, ki Onidajọ Mojisọla Olatoregun to kede isinmi ranpẹ ọlọgbọn iṣẹju lati gbọ ẹjọ miran.

Wọn bi minisita tẹlẹ naa leere pe awọn inawo kan to ṣe nigba naa, eleyii to ni oun ko lee ranti mọ.

O ni ohun ti Fayoṣe beere fun ni oun fi fi owo naa ranṣẹ sii gẹgẹ bi o ṣe han ninu awọn ẹri ti awọn agbẹjọro Fayoṣe gbe kalẹ.

Obanikoro ni ajọṣepọ to dan mọran to wa laarin oun ati Fayoṣe, ko ni lee jẹ ki oun ko tu ọpọlọpọ aṣiri ohun to waye laarin awọn.

Amọṣa, o ni gbogbo ilakaka oun lasiko ti oun wa nipinlẹ Ekiti ni lati rii pe Fayoṣe di gomina ati pe inu oun bajẹ gidigidi lati wa jẹjọ tako Fayoṣe naa bayii.