Àwọn ìgbésẹ̀ tó yẹ láti bá INEC ṣíṣẹ́ ìdìbò 2019

INEC

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, INEC
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ eleto idibo lorileede Naijiria kede lọjọru pe awọn n wa awọn eeyan ti yoo ba wọn ṣiṣẹ lasiko idibo gbogbo gbo ọdun 2019.

Ikede ọhun ti wọn fi si oju opo Twitter wọn salye pe awọn ipo maarun kan lawọn n wa eeyan to kun oju osunwọn fun lẹni ti yoo pese iranwlọwọ lawọn ibudo iforukọsilẹ ati awọn ijọba ibilẹ.

Awọn ipo to wa nilẹ ọhun ni ipo Alamojuto eto idibo( Supervisory Presiding offcer), oludari aye iforukọsilẹ(Registration Area Center -RAC Manager), alamojuto eto ibo(Presiding Officer - PO), igbakeji alamojuto eto idibo(Assistant Presiding Officer ), ati amoju ẹrọ lawọn aye iforukọsilẹ nijọba ibilẹ(Registration Area Technical Support)

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bi o ṣe le kọwe bere fun iṣe naa

Awọn to n wa ipo naa le lọ si oju opo INEC eleyi tii ṣe http://pres.inecnigeria.org/

  • Tẹ aye iforukọsilẹ ki o si tẹle awọn alaye
  • Rii wi pe o yẹ apo iranṣẹ rẹ wo lati mọ wi pe wọn fi oju opo igbaniwọle ranṣe pada si ọ
  • Tẹ oju opo ti o ti ṣe ayewo idanimọ ki o si parọ ọrọ aisri abawole rẹ(password)
  • Kọ awọn iroyin nipa rẹ sinu fọọmu naa ki o si fi aworan fọto pelebe rẹ ranṣẹ
  • Kọ ohun to yẹ nipa awọn oniduro rẹ
  • Buwọlu akọtọ ijẹri (attestation box) ki o si fi iforukọsilẹ fun iṣẹ rẹ ranṣẹ
  • Tẹ iwe ẹrijẹmi pe o ti forukọ silẹ jade
Aworan oṣiṣẹ Inec
Àkọlé àwòrán, Awọn agunbaniro ati oṣiṣẹ Inec miran lasiko idibo

Se gbogbo eeyanlo le forukọ silẹ?

Ṣaaju ki o to bẹrẹ iforukọsilẹ, o ni awọn nnkan to yẹ ki o ni gẹgẹ bi nnkan ti INEC n bere fun.

Ẹnikẹni to ba fẹ forukọ silẹ gbudọ ni apo ifiweransẹ ori ẹrọ ayelujara, e-mail, aworan fọto pelebe ti ko ju 50kb ni iwọn ati adirẹsi awọn oniduro rẹ.

Awọn to n wa iṣẹ gbọdọ ni nọmba ṣiṣe agunbanirọ eleyi to bẹrẹ lati ọdun 2017 pẹlu ami idanimo to koju owo.

Bi o ba n gbero lati forukọ silẹ yara tete nitori iforukọsilẹ yoo dopin lọjọ kọkanlelogun oṣu kini ọdun 2019.