Eko: Wale Oluwo ní ìdìbò abẹ́nú APC tó mẹ́hẹ l‘Eko ló fa sábàmí

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ti sọ wi pe lootọ ni Wale Oluwo to jẹ Kọmisọna eto ohun amusagbara nipinlẹ Eko ti kuro lẹgbẹ oṣelu APC dara pọ mọ PDP.

Wale Oluwo fun ra rẹ s fun BBC pe oun kọwe fi Ambode sil tori bi ẹgbẹ oṣelu wọn, All Progressives Congress ṣe ṣe mọndaru ninu idibo abẹnu wọn nipinlẹ Eko.

O tun sọ pe ''maa dara pọ mọ PDP, maa si ṣiṣẹ fun oludije wọn Jimi Agbaje lati di gomina''.

Kọmisọna feto ohun amusagbara ati ohun alumọọni ilẹ, nipinlẹ Eko, Wale Oluwo ti kọwe fẹgbẹ oselu APC silẹ, to si tun juwọ si ipo rẹ ninu igbimọ alasẹ gomina Akinwunmi Ambọde pe o digbose.

Bakan naa ni Oluwo wa fọwọ gbaya pe oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oselu PDP, Jimi Agbaje, ni oun yoo se atilẹyin fun lati moke ninu eto idibo gomina nipinlẹ Eko.

Oluwo kede ọrọ yii ninu iwe to kọ pe oun ko sisẹ mọ, to si n naka aleebu si awọn asaaju ẹgbẹ oselu APC pe wọn n tẹ ilana eto isel ijọba awa ara wa loju, eyi to sanna fun Babajide Sanwo Olu lati moke ninu ibo abẹnu ẹgbẹ naa l‘Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oluwo fi kun pe idibo abẹnu ẹgb APC to lọw mọkaruru ninu nipinlẹ Eko lo ti ta ẹrẹ nla si ara ẹgbẹ ọhun pẹlu afikun pe, awọn ikọ alagbara kan wa ninu ẹgbẹ naa, ti wọn jẹ igi wọrọkọ to n da ina alafia ẹgbẹ ru nipinlẹ Eko.