You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
2019 Elections: Ilọrin ń gbàlejò Atiku lónìí fún ìpolongo ìbò
Oludije fun ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP, Atiku Abubakar, yoo balẹ silu Ilorin, tii se olu ilu ipinlẹ Kwara fun ipolongo idibo Aarẹ.
Atejade kan lati owo ẹgbẹ oselu PDP ti wọn fi sita loju opo Twitter wọn so pe, ipolongo naa jẹ ti ẹkun aarin gbungbun ariwa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ninu awọn ti ikede naa ni yoo kọwọrin pẹlu Atiku, la ti ri awọn Gomina ẹgbẹ naa, awọn eekan ẹgbẹ to fi mọ ọmọ ẹgbẹ PDP jakejado.
Saaju ni Atiku Abubakar ti gbe ipolongo rẹ lọ si ipinlẹ Sokoto, ti wọn fi sọri iwọ oorun ariwa, ti a si gbo wi pe ipolongo naa yoo kari gbogbo awọn ẹkun idibo orileede Naijiria.
Lẹyin ipolongo ẹkun idibo ni ẹgbẹ naa yoo bẹrẹ ipolongo idibo lo si awọn ipinlẹ lọọkọkan.
Ipinlẹ Kwara ni ipinlẹ ti Aarẹ ile asofin agba Bukola Saraki ti wa.
Oselu ipinlẹ naa si ṣe pataki fun oludije yala fun ipo Aarẹ ni tabi Gomina.
Idi ni wi pe, isakoso ijọba nipinlẹ naa jẹ fa-ki-n-fa laarin ẹgbẹ oselu APC ati PDP.
Lafikun, ni bi nnkan ti ṣe n lọ lenu ọjọ mẹta yi ti ẹgbẹ oselu APC ti ṣe fẹyin ẹgbẹ PDP gbolẹ ninu atundi ibo fun asoju ile asofin to waye eleyi ti wọn fi yan asoju miran rọpọ Funke Adedoyin to salaisi.