FEC: Ìgbìmọ tuntun dìde láti sàtúntò ọlọ̀pàá

Awọn alaṣẹ ijọba

Oríṣun àwòrán, Federal Govt/twitter

Àkọlé àwòrán, Ìjọba bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ àtúntò ọlọ̀pàá

Ìgbmọ tó ń moju to ètò ọrọ̀ ajé ti sàgbé dìde ìgìmọ tẹ̀ẹ́kótó lati mu ojuṣe ilé iṣẹ́ ọlọpàá pín sí ipele.

Olúbádámọran lórí ètò ààbò Babangida Munguno ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ náà lẹ́yìn ìpàdé àwọn aláṣẹ ìjọba, èyí ti adele ààrẹ ọjọ̀gbọ́n Yemi Osinbanjo ní ile ààrẹ l'Abuja lónìí.

Mungono sàlàyé pé Ìbrahim Idris tó jẹ́ ọgá àgbà ọlọ́pàá, ní yóò jẹ́ alága ìgbìmọ tí àwọn asojú ẹkùn mẹfẹ̀fà yóò wà níbẹ̀.

Ó tọ́ka síi pé Nàìjíríà ń koju àwọn ǹkan to lòdí pàápàá jùlọ lórí ètò ààbọ.

Olùbádàmọ̀ràn pàtàkì fún ààrẹ tún fi kún pé ìjọba àpapọ̀ ń mójú to àwọn ìpèníjà míràn tó ń jẹyọ láti ẹ̀yìn odi orílẹ̀-èdè yìí.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ, àwọn ìdojúkọ ètò ààbò yìí ní gbogbo ilé iṣẹ́ elétò ààbò ń ṣe àtòpọ̀ rẹ̀, o fi kún pé àwọn ìgbìmọ míràn yòó tún dìde láti máa ṣe àbẹwò láti rẹyin gbpogbo ìdojukọ lori ààbo

Ìdìbò 2019: INEC fẹ́ ná N6bn lórí ounjẹ fún àwọn ọlọ́pàá

Àjọ́ eleto idibo INEC ni awọn yoo na N6bn sori ounjẹ ti awọn ọlọpàá ti yoo kopa ninu eto idibo gbogboogbo 2019 a jẹ.

Alaga INEC, ọjọgbọn Mahmoud Yakubu ni o sọ bẹẹ nigba ti o gbe eto iṣuna idibo 2019 ti ajọ naa gbé siwaju ile igbimo aṣojuṣofin ni Abuja l'Ọjọru.

Awọn aṣofin naa ti iye owo ọhun ko ba lara mu ti ni ajọ naa gbọdọ ṣalaye bi yoo ṣe na owo naa.

Awọn gomina na N2trn ni ọdun mẹwaa

Bakan naa, igbimọ awọn gomina Naijiria ti ni awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji orilẹ-ede yii na N2trn ni aarin ọdun mẹwaa lati ṣe iranlọwọ for ileeṣẹ ọlọpaa.

Eto idibo 2015

Oríṣun àwòrán, Fedral Govt/ Twitter

Àkọlé àwòrán, Eto idibo 2019 ti n kan ilẹkun

Agbẹnusọ igbimọ naa, Abdulrazaque Barkindo, lo sọ bẹẹ ni Abuja ni ọjọ Iṣẹgun, nibi to ti ṣalaye pe iwadii ẹka igbimọ naa lo fi ọju iye owo naa lede.

O ni, "Ni ọdun 2015, Ipinlẹ Eko nikan, labẹ iṣakoso Gomina Akinwunmi Ambode, na N4.765bn lati ran ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ."

Àkọlé fídíò, 'Ọ̀lọ́wọ́ òsì kọ́ndọ́rọ́'
Àkọlé fídíò, INEC yoo sun miliọnu meje kaadi idibo