Ààrẹ Kenyatta: mi ò kọ̀ láti pàdánù ọ̀rẹ́ tó bá lọ́wọ́ nínú ìwà àjẹbánu

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Olóri àjọ ojurin lorileede Kenya àti àjọ tó ń ri sí ọ̀rọ̀ ilẹ títà ti wọ gau lori pé wọn san owó tó lé ní mílíọ̀nù méjì dọ́là gẹgẹ bí owó gbà mábìnú fún ilẹ̀ tó jẹ ti ìjọba.

Mohammed Abdalla Swazurri alaga àjọ ojurin lorileede Kenya ati Ogbeni Atanas Kariuki Maina wa lara awọn ti iwadi kan so pe nise ni wọn san owo gba mabinu oun lọna eru.

Gbogbo àwọn ti igbá ọ̀rọ̀ náà sí mọ lórí to fi mọ awọn to gba owo naa ní wọn ti pè lẹ́jọ́ pẹ̀lú.

Gbogbo wọn sọ pe àwọn ko jẹ̀bi ẹsun naa.

Ilẹ wo ni wọn ta?

Ilẹ ti wọn ta ọhun jẹ eleyi ti ijọba Kenya ra ni biliọnu mẹ́ta dọ́là pẹ̀lú ìrànwọ́ China láti ṣe ojú irin tí yóò sọ oluulu Nairobi pẹ̀lú ilu ìdíkọ̀ oju omi Mombasa pọ.

Awọn alatako ijọba bẹnu atẹ lu bi ijọba ti se n na owo lori oju irin naa tohun ti bi ọrọ aje ko ti se gun rege fun orileede naa.

Bakaana lawọn ajafẹtọ ẹranko ni oju ọna ti oju irin naa gba yoo se akoba fun ibudo iko ẹranko si Tsavo ati ti Nairobi.

Lẹnu ọjọ mẹta yii, iroyin orisirisi to ni se pẹlu bi awọn osise ijọba ti se n wuwa jẹgudujẹra tan kalẹ lorileede Kenya .

Amọ Ààrẹ Uhuru Kenyata ti kede pe òún o ni kọ láti pàdánù awọn ọ̀rẹ́ oun toba lọwọ ninu ìwà àjẹbánu.