Gómìnà rè sodò nì Kenya nígbà tó ń ya fọ́tò ara rẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọrọ burúkú tòun ẹrín. Afárá já Gómìnà já sodo.

Ṣókí ìròyìn kayefi yíi ree láti orileede Kenya níbi tí Gómìnà Alfred Mutua ti agbegbe Machakos àti àwọn akoroyin méjì, tí wọn já sodo nigba ti afárá tí Gómìnà wa se ìfilọ́lẹ̀ rẹ já.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn Gómìnà Mutua ní ọrọ̀ kò ri bẹẹ.

Bákannáà lójú òpó Twitter rẹ, Gomina Mutua fi ìkìlọ sita pe, oun yóò pé ẹnikẹ́ni to bá gbé ìròyìn eleje nipa ìṣẹlẹ náà lẹjọ.

Ẹfẹ tóun yèyé ní àwọn ọmọ Kenya tun fí da esi pada fún-un lórí Twitter .

Àwọn kan ni, kàkà kí o kọjú mọ awọn tó ṣe iṣẹ ajambaku lórí afárá to já, n sẹ ní ọ n dùn kọkọ mọ àwọn akoroyin.

Èyí kìí ṣe àkọkọ ikọlu láàrin àwọn ará ìlú àti Gómìnà Mutua.

Lai pẹ yi ni ile isẹ iròyìn kan kọ si oju opo Twitter rẹ pe, Mutua sọ pe ''àwọn ilé ìwòsan ti mo kọ, lo mọ jùlọ lorílè-èdè Kenya.''

Ka ṣáà dúpẹ pé, kò sí èmí to ba isẹlẹ naa rin.