You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ijamba ọkọ tirela to sẹlẹ lori afara Kara ni ilu Eko gbẹmi mẹrin
Ọmọdekunrin,ọmọ ọdun marun kan atawọn eeyan mẹta min lo ti jalaisi ninu isẹlẹ ijamba kan to waye laarọ oni lori afara Kara to wa ni opopona marosẹ Ibadan silu Eko.
Bakanaa ni ẹsẹ iya ọmọkunrin to jalaisi ọhun tun ha sinu ile ẹru kan, toto ẹsẹ bata ogun, ti wọn so pọ mọ ọkọ akẹru to jabọ lori afara Kara bọ sinu odo ogun to wa labẹ afara naa.
Iya naa ati ọmọ rẹ ọkunrin to jalaisi yi ni wọn ero inu ọkọ akero kan ko to di pe ijamba naa waye.
Ko tan sibẹ, awọn ero mẹta mii, ti wọn wa ninu ọkọ tirela naa tun ni wọn gba ọna ọrun lọ lasiko ti ọkọ naa jabọ sinu odo Ogun.
Amọ osisẹ alarin fun ileesẹ to n sakoso oju popo nipinlẹ Ogun, Babatunde Akinbiyi ni wọn ti doola ẹmi obinrin ti ẹsẹ rẹ ha sabẹ ile ẹru naa, ti wọn si ti gbe lọ sile iwosan.