Ìjàmbá iná Èkó: Èèyàn méjì wa lẹ́sẹ̀ kan ayé ẹsẹ kan ọrùn

Aworan Ile iwosan isele pajawiri ilu Eko
Àkọlé àwòrán, Ile iwosan isele pajawiri ilu Eko gbalejo eeyan mefa lara awọn to farapa ninu isele naa

Awọn osisẹ pajawiri tí gbè àwọn tó f'arapa nínú ìjàmbá iná ọkọ agbepo Èkó kuro ní Ilé ìwòsan ìṣẹlẹ pajawiri lọ sí ile-iwosan to wa fun awọn to ni ijamba ina to wa ni Gbagada, ni ipinle Eko.

Akoroyin BBC News Yoruba, Kunle Falayi to ṣe àbẹwò sí ilé ìwòsan náà ní àwọn dókítà gbe ìgbésẹ náà kí wọn ba le ri ìtọjú tó péye gbà.

Iroyin ni eniyàn mẹfa ni wọn kọkọ gbé wá sí ilé ìwòsan náà kété ti ìjàmbá naa ṣẹlẹ.

Akọroyin wa jabọ pe, lẹyin ayẹwo, awọn osise ilera gbé èèyàn méjì ti ifarapa wọn pọ pupo ló sì ilé ìwòsan ìjọba to wà ní Gbagada.

Ireti si ni pe awọn mẹrin to ku yoo gba itoju ni ilé ìwòsan ìṣẹlẹ pajawiri titi ti ara wọn yoo fi ya lati pada sile wọn.

Bakan naa, oniroyin wa ri àwọn mọlẹbi bi wọ́n se joko síta ti wọn sì n dúró dé àwọn dókítà mú ìró nípa ìtọjú awọn eeyan wọn wà.

Aworan Ile iwosan isele pajawiri ilu Eko
Àkọlé àwòrán, Àwọn mọlẹbi n dúró dé kí àwọn Dókítà mú ìró wa nípa èèyàn wọn

Amọ, sadede ni wọn ko awọn mẹrin to ku si inu ọkọ ti wọn si wa wọn lo si lọ sí ẹka ti o n tọjú àwọn tí iná jó ni ile iwosan ijoba ni Gbagada.

Akoroyin wá jabo pé oun ko ti i ni aanfaani lati mo boya iye eeyan to ku ninu isẹlẹ naa ti le ni mẹsan.

Èèyàn mẹsan ní ìròyìn kókó sọ pé ọ pàdánù ẹmi wọn nínú ìjàmbá náà tí èèyàn mẹrin sí f'arapa.