Ekiti2018: Fayẹmi ni ìkérora àwọn èèyàn Èkìtì ló mu òun díje

Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, Kayode Fayemi

Àkọlé àwòrán, Fayẹmi ni igbe awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lo mu oun fi pinnu lati gbegba ibo fun gomina

Fayẹmi ìpínlẹ̀ Ekiti di ẹni Ọlọrun kò pa lọ́wọ́ ìbọn

Oludije fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, ti sọ pe, ori lo ko oun ati awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC yọ lọwọ iku ibọn lọjọ Ẹti to kọja.

Fayẹmi ni bi kii ba ṣe ti Ọlọrun ni, o ṣeeṣe ki oun, gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ati aṣofin apapọ tẹlẹri, Ọpẹyẹmi Bamidele ti di oku lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹ.

Fayẹmi ni igbe awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lo ta si oun leti ni oun fi pinnu lati gbegba ibo fun gomina.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ìṣẹlẹ iyinbon APC Ekiti : Ki gaan lo ṣẹlẹ?
Amin iyasọtọ kan

O ni o da oun loju bi àdá pe awọn eeyan ipinlẹ Ekiti ti ṣetan lati bọ lọwọ ohun to pe ni 'isinru' labẹ gomina Ayọdele Fayoṣe.

Ni ọsẹ to kọja ni iro ibọn sọ lálá lati ọwọ ọlọpaa kogberegbe kan, nibi ipade ikinikaabọ ti wọn ṣe fun Fayẹmi ni olu ile iya ẹgbẹ oṣelu APC nilu Ado Ekiti.

Nigba ti ariwo ọhun si rọlẹ ni o di mimọ pe ọta ibọn ti ba aṣofin apapọ tẹlẹri, Ọpẹyẹmi Bamidele, atawọn eeyan marun un miran ti wọn ti di ero ileewosan bayii.